Biden and Harris Inauguration: Ààrẹ Joe Biden tí gba àwọn ọmọ Naijiria láàyé látí wá sàtìpó ní Amẹrika

BIDEN

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ tuntun ni orilẹede Amẹrika, Joe Biden ti gbegi kuro lori ofin to de awọn ọmọ orilẹede Naijiria to fẹ wa ṣe atipo ni orilẹede Amẹrika.

Biden fi aṣẹ tuntun yii lele ninu awọn aṣẹ ofin tuntun marundinlgun to buwọlu laarin wakati mẹrinlelogun ti wọn bura wọle fun un gẹgẹ bi aarẹ Amẹrika.

Aarẹ Donald Trump lo gbegile awọn ọmọ Naijiria lati maṣe le wa si orilẹede Amerika nitori ẹsun iwa ibajẹ.

Bakan naa ni aarẹ Biden fagile aṣẹ to de awọn orilẹede mẹtala Iran, Libya, Somalia, Syria, Yemen, Venezuela, Eritrea, Nigeria, Sudan, ati Tanzania, to jẹ ẹlẹsin Musulumi ati awọn orilẹede ni ilẹ Afrika.

Ninu ọrọ rẹ, Biden ni awọn igbesẹ aarẹ Donald Trump mu ifaṣẹyin ba orilẹede Amẹrika.

Oríṣun àwòrán, AFP

O ni awọn a ri pe awọn ṣe iwadii finifini lori awọn eniyan to ba fẹ wọ ilẹ Amẹrika, amọ awọn ko ni fi ofin de ẹnikẹni.

''Awọn babanla wa lorilẹede Amẹrika gbe orisun ilẹ naa le anfaani lati ṣe ẹsin to ba wu wa pẹlu igbagbọ ninu ilọsiwaju orilẹede Amẹrika''

''Nitori naa aṣẹ ti ko bojumu ni ki aarẹ fofin de awọn eniyan kan lati maṣe wọ orilẹede Amẹrika nitori ẹsin wọn, o buru jai''

Amọ, Biden ni ẹnikẹni to ba dunkoko mọ orilẹede Amẹrika yoo rugi oyin, nitori eto aabo orilẹede naa jẹ oun logun.

Biden tun da orilẹede Amẹrika pada si iṣọkan awọn orilẹede lori oju ọjọ, iyẹn Paris Climate agreement.

Kókó mẹ́rìn tí Joe Biden ṣetán láti ṣe àti bó ṣe lè kàn ọ́

Joe Biden ti dí ààrẹ tuntun lórílẹ̀-èdè Amerika ni àná nigba ti o ṣe ibura loju gbogbo aye.

Nibi ibura naa ni Joe Biden ti ṣeleri awọn nkan to ṣe pataki sawọn ara ilu.

Oríṣun àwòrán, AFP

O ni oun ṣe ileri lati jẹ aarẹ fun gbogbo eeyan America, eyi tumọ si pe gbogbo ọmọ Naijiria to ti ni iwe igbelu gẹgẹ bii ọmọ America naa yoo gbadun aarẹ Biden to ba mu ileri rẹ ṣẹ.

Ati pe gbogbo awọn ọmọ Naijiria to ba n gbe ni ameirca ni eyi naa yoo tun kan.

Joe Biden rọ awọn eeyan lati maa ni ifarada si ọmọlakeji wọn ki ifẹ ati iṣọkan le jọba.

Eyi tumọ si pe ọkan gbogbo ọmọ Naijiria to wa ni America ati awọn to fẹ lọ sibẹ yoo wa ni alaafia lai lewu

Àkọlé fídíò,

America Inauguration Joe: Wo àwọn eré orí ìtàgé tí Donald Trump ṣe kó tó fi ipò aàrẹ sílẹ̀

Joe Biden tun ni pe: A nilo ara wa, ki agbe ọrọ oselu ti sẹgbẹ kan, ki a moju to ọrọ Coronavirus to n gab ẹbọ lọwọ gbogbo agbye yii.

Eyi tumọ si pe ti a ba ri ojutu si iṣoro ọrọ Covid 19 yoo jẹ ki gbogbo ọmọ ile iwe pada, ki ọkan tonile talejo si balẹ ni orilẹ-ede koowa wọn.

Àkọlé fídíò,

US Vice President:Ẹ wo ìtàn obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò jẹ igbákejì Ààrẹ ilẹ́ Amẹrika?

Joe mẹnuba ina ti America ti la kọja ti wọn si ti bori pẹlu ireti pe wọn yoo dide pada laipẹ ṣugbọn ifẹ omọlakeji lo ṣe koko.

Eyi tumọ si pe ti gbogbo awọn olugbe America ba fi ifẹ gbe wọn yoo jẹ awokọṣe rere fun gbogbo agbaye.

Awọn eeyan Naijira to n gbe nibẹ yoo wa ni alaafia lailewu.

Joe Biden ti dí ààrẹ tuntun lórílẹ̀èdè Amerika:

Aarẹ orilẹede Amerika, Joe Biden ni ijọba tiwantiwa ti jọba lorilẹede Amerika.

Biden sọ eyi lasiko ti wọn n burawọle fun un gẹgẹ bi aarẹ karundinlaadọta lorilẹede Amerika.

Oríṣun àwòrán, AFP

Donald Trump to kuro lori oye ko gba wi pe Biden lo wọle gẹgẹ bi aarẹ nitori naa ko lọ si ibi iburawọle naa.

Awọn eniyan jankan jankan bi Barack Obama, Hillary Clinton ati ọpọlọpọ eniyan lo wa nibi iburawọle ohun.

Saaju ki wọn to burawọlẹ fun Biden ni wọn ti burawọle fun igbakeji rẹ, Kamala Harris to jẹ obinrin akọkọ ti yoo di ipo naa mu ni orilẹede Amẹrika.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Biden inauguration: Báyìí ni White House ṣe múra sílẹ̀ de àárẹ tuntun

Eto igbẹjọba silẹ ni ọdun yii nilẹ America yatọ si awọn to ti n waye tẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Idi ni pe ni kete ti idibo ba pari, ni eto naa ti ma n bẹrẹ, sugbọn ọsẹ diẹ lẹyin eto idibo ni igbesẹ to bẹrẹ, nitori pe Aarẹ Trump kọ esi idibo naa.

O si ti sọ pe oun ko ni i lọ fun ayẹyẹ gbigbe ijọba fun Biden.

Sibẹsibẹ, eto naa yoo waye gẹgẹ bi ìṣe rẹ.

Eeyan bi ẹgbẹrun mẹrin ti Aarẹ Trump gba sisẹ ninu isejọba rẹ ni yoo padanu isẹ wọn, ti Biden yoo si fi awọn miran rọpo.

Lasiko ti ijọba tuntun ba fẹ ẹ bẹrẹ, eeyan bi ẹgbẹrun lọna àádọ́jọ si ọọdunrun lo ma n kọwe beere fun awọn isẹ naa, gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ to n mojuto ayipada ijọba ni Amerika ṣe sọ.

Àkọlé fídíò,

Joe Biden Innauguration: Tani ìyàwó Joe Biden tí yóò jẹ obìnrin akọ̀kọ nílẹ̀ Amẹrika?

Gẹgẹ bi Onkọwe nipa bi igbeaye ṣe ri nile ijọba ilẹ America, Kate Anderson ṣe sọ, àwọn aga ati tabili, to fi mọ awọn nkan eelo mii to wa ni White House kii yipada lati ijọba kan si ijọba tuntun.

Sugbọn awọn nkan mii bi aworan to jẹ ti Aarẹ to n fi ipo silẹ, yoo kuro.

Àkọlé fídíò,

Akomolede ati Asa: Alagba Ajibola láti Fakunle ní olùkọ́ wa lórí ètò ìró lónìí

Ni ọ̀tẹ̀ yii, isẹ atunse nla ni yoo waye nile ijọba naa, nitori pe ọpọ eeyan, to fi mọ aarẹ Trump lo ni coronavirus lasiko kan.

Agbenusọ fun ẹka to n sakoso ile ijọba naa, sọ pe gbogbo kọọrọ ati gbangba ibẹ ni yoo jẹ fifọ dáadáa, pẹlu oogun apakokoro.