Ogun: Ọkùnrín márùn ún fojúbalé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ijà àti igbó fífà

Ogun

Oríṣun àwòrán, Google

Ọkunrin marun un ti yọju si ileẹjọ ni ilu ọta, nipinlẹ Ogun lẹyin ti wọn fẹsun kan wọn pe wọn n lo oogun oloro ni gbangba.

Awọn ọkunrin marun un ọun ni Popoola Idris, 21; Efikioyha Tunwemi,26; Akanji Jimoh,30; Omodewu Monday,36 ati Akinwandi Nureni,28,amọ ti wọn ko fi adirẹsi wọn lede.

Ẹsun ti ileeṣẹ ọlọpaa fi kan wọn ni wi pe wọn n da igboro ru, ti wọn si n fa oogun oloro bii cannabis, indian hemp ni agbegbe Ijoko ni Ọta.

Agbẹjọrọ ijọba, Emmanuel Adaraloye ni Ọjọ Kẹtadinlọgbọn , Oṣu Kini ni iṣẹlẹ ọun waye ni ilu Ọta, ti awọn ti wọn fẹsun kan naa si n ba ara wọn ja ni gbangba.

O fikun un wi pe iṣẹlẹ naa ti da rogbodiyan silẹ ni agbegbe ọun, ti awọn eniyan si n foya ni agbegbe ọhun.

Àkọlé fídíò,

World Cancer Day: Mo pàdánù ọkọ àti ọ̀rẹ́ bí mo ṣe ni 'Cancer'- Iwalade Adebimpe Adetunji

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ni wọn n da alaafia ilu ru, ti wọn si huwa to le fa ipaya ni agbegbe wọn.

Amọ, awọn ti wọn fẹsun kan naa ni awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn.

Magisreti A. O Adeyemi wa gba beeli wọn ni iye owo ẹgbẹrun lọna aadọta naira, pẹlu oniduro kọọkan.

Adeyemi ni awọn oniduro wọn naa gbọgbọ ma a gbe ni ilu Ọta, ki wọn si ni iṣẹ lọwọ, eyi ti yoo fihan pe wọn n san owo ori wọn deede.

Àkọlé fídíò,

Ìtanijí lórí BBC Yorùbá: Odú Iwori Obara bá wa sọ̀rọ̀ lórí ìfaradà tó pọ̀

Ọ̀rọ̀ ìfẹ́ mú àgùnbánirọ̀ di èrò iléẹjọ́ ní ìpínlẹ̀ Kogi

Agunbanirọ kan ni ipinlẹ Kogi, Sam Abiola ti wa ni ile ẹjọ pẹlu arakunrin Adebiyi Sodiq, lẹyin ti wọn fẹsun kan pe o lu u ni jibiti ifẹ.

Oríṣun àwòrán, NYSC/TWITTER

Ni Ọjọ Aje ni wọn gbe awọn mejeeji lọ si ileẹjọ giga ni ipinlẹ Kwara to wa ni Ilorin lori ẹsun pe wọn lu obinrin ni jibiti ifẹ.

Ileeṣẹ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹ-ede Naijiria, EFCC ni ilu Ilorin lo gbẹ awọn mejeeji lọ si ileẹjọ lori ẹsun oniga mẹrin.

Awọn mejeeji ti wọn fi ẹsun kan naa jẹwọ pe lootọ ni awọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn.

''Iwe ipẹjọ naa ni Sam Abiola sọ wi pe orukọ oun ni Missie Bonie lati fi parọ gba owo lọwọ ọrẹkunrin rẹ, Rick to si gba owo ni ọwọ rẹ.''

''Iye owo ti wọn si gba lọwọ rẹ jẹ $550, iye owo dọla ilẹ okeere, to si jẹ ki o ro wi pe, oun ni ifẹ rẹ denudenu.''

Àkọlé fídíò,

Akomolede ati Asa Ondo: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelo

''Bakan naa ni Adebiyi Sodiq naa pe ara rẹ ni Maria ti to si tun pa irọ gba owo ni ọwọ arakunrin ọhun.''

''Eyi lodi si ofin orilẹ-ede Naijiria, ti iya si tọ si ẹnikẹni to ba ṣe gbajuẹ, to si tẹ oju ofin orilẹede Naijiria mọlẹ.''

Ninu idajọ rẹ, Adajọ Adenike Akinpẹlu ti sun igbẹjọ si Ọjọ Kọkanla, Osu Keji, ọdun 2019.