Myanmar coup: Kéte tí wọ́n gba ìjọba tán ní Myanmar ni ológun ti ojú òpó facebook pa

Facebook

Oríṣun àwòrán, @Facebook

Awọn ologun ilẹ Myanmar ti kede pe ko si olugbe orilẹ-ede naa to maa le lo oju opo ikansira ẹni facebook lasiko yii.

Wọn ni awọn gbe igbesẹ yii ki alaafia le jọba lẹyin ti wọn gba ijọba nibẹ.

Oju opo facebook tobi pupọ nibẹ.

Awọn aṣojuṣofin kọ lati fi ile wọn silẹ ni olu ilu Myanmar ni Yangon.

Ogagun Aung Hlaing to ṣaaju awọn ọmọ ogun to gabjọba naa lo fopin si iṣejọba alagbada to waye fun igba ranpẹ nibẹ.

Bayii, wọn ti sọ aarẹ Myint ati olori awọn adari Aung San Suu Kyi si gbaga pẹlu ẹsun to pọ ti wọn si ti bẹrẹ si ni jẹjọ lọjọ Ru.

Wọn ni wọn n fi ẹrọ walkie-talkie sọrọ gegẹ bi ẹsun kan ati pe aarẹ Myint tapa si ofin Covid 19 lasiko ipolongo ibo loṣu kọkanla.

Àkọlé fídíò,

Akure incest Momoh Usman case: Láti ẹni ọdún mẹ́tàlà ni Bàbá mi ti ń ba mi sùn- Fatimah Us

Igba wo ni wọn maa ṣi facebook pada nibe?

Awọn ọmọ ogun naa kede pe ko i tii ya.

Àkọlé fídíò,

Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ

Ileeṣẹ to n risi eto ibanisọrọ ni Myanmar ni od i ọjọ kere, oṣu keji ki wọn to ṣi oju opo naa pada.

O le nilaji eeyan Myanmar to to miliọnu mérinlelaadọta eeyan to n lo oju opo facebook.

Mọ̀ síi nípa Aung Suu Kyi tí wọ́n sọ sẹ́wọ̀n ní Myanmar àti bí ìgbàjọba ṣe wáyé níbẹ̀:

Myanmar: Nibo lo wa? Tani Aung Suu Kyi ti wọn sọ sẹwọn ati nkan mẹwaa mii to yẹ ko mọ nipa ilẹ Asia yi

Àkọlé fídíò,

World Cancer Day: Mo pàdánù ọkọ àti ọ̀rẹ́ bí mo ṣe ni 'Cancer'- Iwalade Adebimpe Adetunji

Mọ̀ síi nípa Aung Suu Kyi tí wọ́n sọ sẹ́wọ̀n ní Myanmar àti ìjìyà tuntun tí Joe Biden kéde fún wọn.

Aarẹ Amẹrika Joe Biden ti sọ pe oun yoo gbe ijiya tuntun ka ori orileede Myanmar lẹyin tawọn ọmọ ologun ilẹ naa ditẹ gba ijọba.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Laipẹ yi ni Amẹrika dẹkun diẹ lọrun Myanmar pẹlu awọn ijiya to wa nilẹ lẹyin ti wọn ri pe Myanmar yi pada si ijọba alagbada lati ijọba ologun ti wọn wa lọjọ pipẹ.

Lọjọ Aje yi ni awọn ologun sọ olori ijọba Aung San Suu Kyi ati awọn alasẹ mii si gbaga ti wọn si fẹsun kan ẹgbẹ oselu arabinrin Suu Kyi pe wọn se magomago ninu idibo ti wọn jaweolubori.

Orileede UK, ajọ UN ati naa ti bẹnu atẹ lu iditẹgbajọ yi ti wọn si ni o le da ifẹhonuhan ati iwọde silẹ.

Arabinrin Suu Kyi, ẹni to ti fẹẹ lo ọdun mẹẹdogun lẹwọn tẹlẹ laarin ọdun 1989-2010, ti kesi awọn alatilẹyin rẹ lati wọde tako iditẹgbajọ to waye yi.

O fi ọrọ yi sita ninu iwe kan to kọ saaju ki wọn to fi si atimọle.

Àkọlé fídíò,

Ọdún kan lẹ́yìn ogun musulumi Rohingya, ìbànújẹ̀ dorí àgbà kodò

Nise lo kilọ pe iwa tawọn ologun hu yi le ko ifasẹyin ti yoo to ọdun mẹẹdogun ba orileede naa.

Awọn ọmọ ologun kọ lati gba esi abajade idibo to waye ni osu Kọkanla ọdun to kọja, ti wọn si ni awọn gbe ofin pajawiri ọlọdun kan lelẹ.

Àkọlé fídíò,

Myanmar: kékeré ni wọ́n ti n kọ́ àwọn ọmọ nípa ọ̀nà oge ṣiṣe

Bi a ti se n sọrọ yi, wọn ti gba gbogbo awọn minisita ati igbakeji wọn kuro lori ipo to fi mọ minisita feto ilera, isuna, ọrọ abẹle ati minisita fọrọ ilẹ okeere.

Sugbọn ninu atẹjade lati ọdọ aarẹ Amẹrika Joe Biden, o ni ''ko yẹ kawọn ologun fipa yi ero ọkan ara ilu pada tabi ki wọn fi pa abajade esi ibo to yanrantin rẹ''.

Àkọlé fídíò,

Big breast: Oluwatosin Adegboro, Oluwaseun Amoo, Remi Fatolu: Ẹlòmíì ń fi irú ọyàn wa tọrọ

Laarin ọdun mẹwaa to kọja yi ni Amẹrika bẹrẹ si ni yọ awọn ijiya ti wọn saaju gbe kari Myanmar nitori bi wọn se n tẹsiwaju ninu ijọba awarawa.

Biden ni awọn yoo yara ''sagbeyẹwo ọrọ to wa nilẹ yi'' ati pe''Gbogbo ibi ti wọn ba fẹ doju ijọba awarawa bolẹ ni Amẹrika yoo ti gbaruku ti ara ilu ''.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn nkan mẹwaa ree to yẹ ni mimọ nipa Myanmar:

Myanmar, ti a tun mọ si Burma jẹ orileede tawọn akẹgbẹ rẹ pa ti sẹgbẹ kan nitori bi ijọba ologun ti se gbalẹ nibẹ lọjọ to ti pẹ.Laarin 1962-2011 nijọba ologun ti fidi rinlẹ lorileede yi.

Myanmar wa ni apa iwọ oorun guusu Asia ti wọn si ni to ẹya orisirisi to fẹ ẹ to ọgọrun kan.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn orile-ede ti wọn jijọ pa aala ibode papọ ni India, Bangladesh China, Laos ati Thailand.

1057 - Ọba Anawrahta se ifilọlẹ Myanmar ni ipinlẹ Pagan to si fofin de ẹsin Theravada Buddhism gẹgẹ bi ẹsin ti ilẹ naa yoo maa tẹle.

1531 - Labẹ akoso Toungoo dynasty, wọn tun ilẹ naa so papọ ti wọn si sọ ni orukọ Burma.

1885-86 - Asiko yi ni Burmafi wa labẹ akoso ijọba amunisin ilẹ Gẹẹsi.

1948 - Burma gba ominira lọwọ ilẹ Gẹẹsi lọdun taa n wi yi.

1962 - Awọn ologun gba ijọba ti wọn si n seto ijọba ẹlẹgbẹ oselu kan lẹka isejọba ta mọ si ''single-party socialist system.''

1990 - Egbẹ́ alatako Opposition National League for Democracy (NLD) jaweolubori ninu idibo sugbọn awọn ologun ko gba esi ibo yi wọle.

Oríṣun àwòrán, AFP

2011 - Awọn ologun gbe ijọba kalẹ falagbada lẹyin abajade ibo to waye lọdun to kọja.

2015 - Idibo waye. Egbẹ alatako Opposition National League for Democracy ti Aung San Suu Kyi jẹ olori fun jaweolubori lati le seto ijọba iru eyi taa mọ ''parliamentary system'' .

2018 osu Kẹjọ -Ajọ isọkan agbaye UN fẹsun kan Myanmar pe wọn n pa awọn musulumi Rohingya nipakupa.

2021osu Keji - awọn ọmọ ologun ditẹ gbajọba.