World Cancer Day: Mo pàdánù ọkọ àti ọ̀rẹ́ bí mo ṣe ni 'Cancer'- Iwalade Adebimpe Adetunji

World Cancer Day: Mo pàdánù ọkọ àti ọ̀rẹ́ bí mo ṣe ni 'Cancer'- Iwalade Adebimpe Adetunji

Ayé kò parẹ́ nítorí pé ó ni 'Cancer'- Iwalade

Lati kekere ni ọyan ti n kan mi ṣugbọn a ko kaa si rara nigba naa.

E ma binu Madam, a maa ge ọyan yin ni ọrọ ti dokita sọ si mi nigba naa.

Nigba ti Cancer de, O ku emi ati ọmọ, koda, igbeyawo mi to ti n ni wahala tẹlẹ sọnu- Iwalade Adebimpe Adetunji

Iwalade sọrọ lori iriri rẹ to fi bori arun jẹjẹrẹ ati gbogbo ohun to ṣẹlẹ sii.

O ni nigba ti o ya ni oun rii pe omi maa n deede yọ lori ọyan oun ki oun to di ero ile iwosan ni eyi ti wọn ti fi bẹrẹ itọju arun jẹjẹrẹ fun oun.

O ni koko bii ori biro ni wọn kọkọ ri ti wọn si fi iṣẹ abẹ yọ ko to pada wa ni ilọpo mẹrin ki wọn to wa kuku ge ọyan naa kuro.

Iwalade ṣalaye pe bi o tilẹ jẹ pe Baba, Iya ati ẹgbọn oun jẹ dokita sibẹ arun jẹjẹrẹ ọyan fi oju oun ri to ki oun to jajabọ lọwọ arun jẹjẹrẹ ọyan.

Adebimpe gba awọn eeyan nimọran pe: Too ba ti tete mọ pe o ni cancer ki o tete bẹrẹ si ni gab itọju ni.

O ni ki eeyan ma ṣe daadaa nitori o ko mọ ẹni to maa duro ti ẹ nigba iṣoro bii ti oun .

Inu mi dun pe dokita ko sọ pe Madam ẹ ma binu, oṣu kan lo ku fun un yin laye- Iwalade

O ni nitooto adura n gba, ṣugbọn ki agbe igbesẹ to yẹ fun itọju lai duro ti ororo adura nikan.