Akure incest Momoh Usman case: Láti ẹni ọdún mẹ́tàlà ni Bàbá mi ti ń ba mi sùn- Fatimah Us

Akure incest Momoh Usman case: Láti ẹni ọdún mẹ́tàlà ni Bàbá mi ti ń ba mi sùn- Fatimah Us

Titi di isinyi, O dabi pe ki n pokunso ni- Momoh Usman to n ba ọmọ ẹ sun ni Akure.

Baba Fatimah, Momoh Usman lo ti n bẹ gbogbo abiyamọ agbaye lati dari ji oun nitori pe oun ba ọmọ oun obinrin sun.

Fatimah Usman to fi fidio kan sita laipẹ lori ayelujara pe o ti su oun.

Fatimah ṣalaye fun BBC pe ọmọ ọdun mẹtala ni baba oun ti n ba oun sun pẹlu ipa ninu ile

Koda, o ṣalaye bo se kọkọ ṣẹlẹ ni igab akọkọ ninu ile idana ni isalẹ ile wọn.

Fatimah mẹnuba ọpọlọpọ idunkooko mọ ni ti baba oun n ṣe fun oun ki oun to sa kuro nile.

O n beere fun idajọ ododo bayii ti ọrọ naa ti de ile ẹjọ ni Akure ni ipinlẹ Ondo.

Temitope Daniyan to jẹ agbẹnusọ aya gomina Akeredolu naa sọ ipa ti ajọ idabobo ọmọbinrin n ko bayii.

Bakan naa ni Agbofinro Tee-Leo Ikoro naa ṣalaye ni kikun igbesẹ ofin lori ọrọ naa.