Ondo Fulani Herdsmen: Àgbẹ̀ mẹ́ta ni àwọn Fulani darandaran tún pa ní Ọ̀wọ̀, nípińlẹ̀ Ondo

Ondo Fulani Herdsmen: Àgbẹ̀ mẹ́ta ni àwọn Fulani darandaran tún pa ní Ọ̀wọ̀, nípińlẹ̀ Ondo

Ijọba ipinlẹ Ondo ti fi fi lede pe awọn Fulani darandaran tun ti pa agbẹ mẹta nipinlẹ Ondo.

Oluranlọwọ Pataki fun Gomina Akeredolu lori ọrọ awọn agbẹ, Akin Olotu lo fidi ọrọ naa mulẹ.

O salaye wi pe awọn agbẹ lo ji ohun lori ibusun loni lati kegbarẹ wi pe awọn darandaran tun ti ṣekọlu si awọn agbẹ to wa ninu igbo ijọba, ni ilu Ọwọ, nipinlẹ Ondo.

O fi daju wi pe ẹmi agbẹ mẹta lo ba iṣẹlẹ naa lọ.

Amọ agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro ni lootọ ni iṣẹlẹ naa waye, amọ eniyan kan ni wọn pa.

Ati wi pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa, ti awọn ko si le fi idi rẹ mulẹ pe awọn Fulani darandaran ni awọn ọdaran yii.