Amitolu Shittu, ọ̀gá àjọ Amotekun l'Ọṣun wọ gàù nítorí ọ̀rọ̀ tó sọ nípa àwọn olùrànlọ́wọ́ Gómìnà Oyetola

Amitolu Shittu

Oríṣun àwòrán, Amitolu Shittu/facebook

Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti paṣẹ fun oludari ajọ Amọtẹkun nipinlẹ naa, Ọgbẹni Amitolu Shittu, lati farahan niwaju igbimọ olubaniwi ti ijọba gbe kalẹ.

Ẹsun ti wọn fi kan Ọgbẹni Amitolu ni pe o sọ ọrọ ẹgbin si meji lara oluranlọwọ Gomina Gboyega Oyetọla, lori ayelujara Facebook.

Iroyin sọ pe Shittu kọ sori Facebook pe olori oṣiṣẹ fun gomina, Ọmọwe Charles Akinola ati Oludamọran pataki lori eto aabo, Arabinrin Abiodun Ige, ko koju osunwọn.

Àkọlé fídíò,

Amotekun Osun: A ò gbé Amotekun kalẹ̀ láti máa yọjú sí ọ̀rọ̀ tí kò sí lábẹ́ òfin

Kọmisanna fun eto iroyin nipinlẹ Ọṣun, Arabinrin Funke Egbemode sọ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Satide, pe Akọwe ijọba ipinlẹ naa, Ọmọọba Wole Oyebamiji ni yoo dari igbimọ naa.

Wọn si gbọdọ pari iwadii laarin ọjọ mẹta.

O ni "Amitolu fi awọn ẹsun to lagbara kan awọn kan ninu igbimọ oluṣako ijọba Gomina Oyetola pe ọpọlọ ri ibi to tutu ba si ati agbaana ni wọn jẹ fun ijọba.

Ati pe ipo ti wọn wa ko tọ si wọn."

Ṣugbọn ṣa, Shittu ti pa ọrọ naa rẹ kuro ni oju opo Facebook rẹ.

Ninu ọrọ to pada ba BBC sọ, Arabinrin Egbemode sọ pe igbimọ naa ti ṣe ipade, o si ti ṣetan lati jabọ fun gomina.

"Ija inu ile ni ọrọ naa, a si ti yanju rẹ".