Ogun Amotekun: Dapo Abiodun fa ikọ̀ aláàbò létí láti ṣọ́raṣe lórí ìkọjá àyè

Oríṣun àwòrán, Twitter/Dapo Abiodun
Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapo Abiodun ti kilọ fun ikọ Amọtẹkun pe ki wọn tẹ ilẹ jẹjẹ ni ipinlẹ naa.
Dapo Abiodun lọ sọrọ yii nibi eto ifilọlẹ ikọ eleto aabo ilẹ Yoruba naa ni ilu Abeokuta, nipinlẹ Ogun.
Abiodun ni igbeṣẹ awọn gomina ni iwọ oorun Naijiria, lati da ikọ naa silẹ ni awọn ipinlẹ to wa ni ilẹ Yoruba ni ọdun 2020, ni lati dẹkun iwa ọdaran.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Gbàjarè! Ọ̀gá ọlọ́pàá fi ìwé ìpè àti géńdé 15 ránṣẹ́ wá mú mi - Sunday Igboho pariwo
- Ó ṣeéṣe kí ọkọ̀ òfúrúfú ọmọgun Alpha Jet tó pòórá tí já - NAF
- Ọ̀pọ̀ Sunday Igboho, Nnamdi Kanu ní yóò díde torí ìpànìyàn ojoojúmọ́
- Wo ìdí tí wọ́n fi n pé ayájọ́ ọjọ́ òní ni 'Good Friday'
- Alágbe ni olórin, ọ̀rọ̀ Wasiu Ayinde tó fẹ́ kí Yorùbá du ipò ààrẹ kò tó pọ́n - Gani Adams
- Oluwo, tí wọ́n bá rán ọmọ níṣẹ́ ẹrú, kó fi t'ọmọ jẹ - Gani Adams
- April Fool lásán ni o! N kò fi iṣẹ́ tíátà sílẹ̀ láti ṣe òṣèlú - Muyiwa Ademola
O ni awọn ikọ eleeto aabo Amọtẹkun naa gbọdọ ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo to ku, ki eto aabo le gbooro si.
Oríṣun àwòrán, Twitter/Dapo Abiodun
''Ẹ gbọdọ mọ wi pe abẹ ofin ni ikọ Amọtẹkun wa, ẹ o gaju ofin loo nitori naa ẹ tẹlẹ ofin to rọ mọ eto aabo ni ipinlẹ Ogun''
''Mọ ni igbagbọ ninu yin lati ṣe iṣẹ yii bii ṣẹ nitori naa e pese aabo fun ẹmi awọn araalu ati Dukia wọn''
Oríṣun àwòrán, Twitter/Dapo Abiodun
Gomina Abiodun ti wa yan Ọjọgbọn Wole Soyinka gẹgẹ bi asaaju ogun pataki (Special Marshal ) fun ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ naa.
Ninu ọrọ tirẹ, Ọjọgbọn Soyinka rọ gomina lati maṣe ri ikọ Amọtẹkun gẹgẹ bi awọn to fẹ gba iṣẹ mọ awọn ẹṣọ alaabo miran, to wa ni agbegbe naa lọwọ.
Oríṣun àwòrán, Twitter/Dapo Abiodun
Gomina Abiodun wa rọ awọn araalu lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ikọ Amọtẹkun, nipa fifun wọn ni iroyin nipa iwa ọdaran to ba ṣẹlẹ ni agbegbe wọn.z
Oríṣun àwòrán, Twitter/Dapo Abiodun
Bakan naa ni gomina ipinlẹ Ogun naa rọ ikọ Amọtẹkun lati maṣe tẹ ẹtọ awọn eniyan mọlẹ lasiko ti wọn ba n ṣiṣẹ wọn.