Herdsmen-Farmers Clash: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ó le jẹ́ pé àwọn afurasí ọ̀daràn náà padà wá gbẹ̀san ni

Fulani darandaran

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn afurasi Fulani darandaran ti ṣekọlu tuntun si agbegbe Igangan ni ijọba ibilẹ Ibarapa ni ipinlẹ Oyo.

Iwe iroyin Punch ni ọsan Ọjọ Ẹti ni awọn darandaran naa ṣe ikọlu si Arakunrin Ojedokun Ogunmodede to jẹ ọga ileewe to ti fẹyinti.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni wọn ko le e sọ idi ti iṣẹlẹ naa fi waye, nitori ko si ija laarin awọn darandaran ati Ojẹdokun ti wọn ge ọwọ rẹ mejeeji.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Akọwe ẹgbẹ awọn agbẹ ni Ibarapa, Ibarapa Farmers Union, Taiwo Adeagbo ti gbogbo mọ si Akọwe agbẹ ni ibatan oun ni ẹni ti wọn ṣekọlu si.

Oríṣun àwòrán, Others

'' O ṣeni laanu pe awọn Fulani darandaran ko dẹyin lati ma a ṣekọlu si awọn eniyan ati agbẹ Ibarapa.''

''Mo pe ileeṣẹ ọlọpaa nigba ti iṣẹlẹ naa waye, ti kọmiṣọna ọlọpaa si ni ki n fi to awọn ọlọpaa leti''

''Awọn ọlọpaa wa si ibi iṣẹlẹ naa amọ wọn ko le wo awọn aworan naa nitori o buru jai, ẹran ara kekere lo so ọwọ naa mu ti ko jẹ ki ọwọ mejeeji jabọ.''

''Wọn ti ba aye arakunrin naa jẹ nitori o ku diẹ bayii ki ọwọ naa ma jabọ silẹ.''

Àkọlé fídíò,

Pure Water Lylon Art: Adejoke ní ohun èlò ta fi ọ̀rá ṣe ń ní àlòpẹ́, kìí tètè jẹ

Ninu ọrọ tirẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi ni ija igbẹsan lo seese ko waye laarin awọn Fulani darandaran naa ati awọn ọdọ ni ilu Igangan.

O ni iroyin to tẹ ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ ni awọn Fulani darandaran kan ṣe ikọlu si ọkunrin kan ninu oko rẹ, ti wọn si ṣe ijamba si ọwọ rẹ''

Nibayii, ọkunrin naa ti wa ni ileewosan nibi to ti n gba iwosan lọwọ ni Igboora.

Bakan naa ni awọn ọlọpaa ti dẹkun rogbodiyan to suyọ naa laarin awọn ọdọ ati awọn Fulani darandaran ki alaafia le jọba.