Sunday Igboho: Oloye Toluwalase ti ìlú Àjàṣé-Ilé ní ẹ̀wọ̀n ní ìjìyà fún ṣiṣe ayédèrú ''Passport'' ní Benin Republic

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Others

Ọkan gboogi lara awọn oloye ni orilẹede Port Novo ti ni to ba jẹ lootọ ni Sunday Igboho ṣe ayederu iwe irina Benin Republic, yoo fi ẹwọn jura.

Oloye Toluwalaṣẹ ti ilu Ajaṣẹ ile, to tun jẹ aṣoju awọn lọbalọba ti ilu olominira Benin Republic lo sọ bẹẹ lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ.

Oloye naa salaye lori igbiyanju awọn lọbalọba lorilẹede Benin Republic lori ọrọ Sunday Igboho.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oloye Toluwalaṣẹ ni ilu Benin Republic jẹ ilu kan to kere amọ ti ofin wọn gbona jainjain, paapaa lori igbeṣẹ lati gba iwe ọmọ ilu, iyẹn ''Passport''

Oloye Toluwalaṣẹ, ẹni to tun sọ awọn ọna ti wọn n gba lati ri iwe irinna ni orilẹede Benin Republic, wa salaye lẹkunrẹrẹ idi ti Sunday Igboho fi ṣẹ si ofin lori ayederu iwe irnna to lo na.

Kilo de ti Sunday Igboho yoo fi ṣẹwọn lori gbigba iwe irinna ilẹ Benin Republic?

Nigba to n salaye idi ti ẹwọn fi n duro de Igboho to ba jẹ pe lootọ lo gba iwe irinna orilẹede Benin, to si jẹ lọna ayederu, Oloye Toluwalasẹ ni awọn to ba ajijagbara seto iwe irinna naa, yoo fi ara gba ninu ẹwọn ọhun pẹlu.

Bakan naa lo salaye pe ko seesee fun ẹnikẹni lati gba iwe irina silẹ okeere ni Benin Republic, lai kọkọ gba iwe ẹri pe ọmọ orilẹede naa lo jẹ, eyiun National Identity Card, NIC.

Àkọlé fídíò,

Sunday Igboho: Ladoja ní bí ìjọba kò bá fi ẹ̀lẹ̀ ṣe, ọ̀pọ̀ ajìjàgbara míì yóò dìde

Ẹnikẹni to ba jẹ ọmọ onilu, ti ko ni kaadi National Identity, ko le gba iwe irinna silẹ okeere, to ba gba lọna ayederu, ewu nla n duro de onitọun, o si le la ti ẹwọn lọ.

''Ẹ jẹ ki n fi ọrọ ara mi ṣe apejuwe lori iwe irinna. Ọmọ bibi orilẹede Benin Republic ni mi, ọmọ ilu Ijẹbu lati orilẹede Naijiria ni iyawo mi, to si bi ọmọ marun un fun mi, mẹta si Benin, meji si Naijiria.''

''Ohun ti mo fẹ ki ẹ mọ ni pe ọmọ mẹta ti mo bi si Benin nikan lo ni aṣẹ si iwe idanimọ, National Identity Card ti orilẹede Benin, awọn ọmọ mi mejeeji ti wọn jẹ ọmọ Naijiria ko ni aṣẹ si iwe irinna naa.''

''Iyawo mii gan an to bi awọn ọmọ naa fun mi ko ni aṣẹ si awọn iwe irinna yii, afi igba ti a ba ṣẹṣẹ lọ ṣe igbeyawọ oloruka ni kootu ti orilẹede Benin Republic, nikan lo laṣẹ si iwe idanimọ National Identity card orilẹede Benin.''

Àkọlé fídíò,

Ilorin Cripple Couple: Ọṣẹ ìfabọ́ ni tọkọ-taya tó ní ìpèníjà ẹsẹ̀ ń tà láti bọ́ ọmọ mẹ́ta

''Ko tan si bẹ o, lẹyin igbeyawo naa fun bii oṣu melo abi ọdun diẹ, ni yoo ṣẹṣẹ bẹrẹ igbeṣẹ lati gba iwe irinna naa.''

''Ọna kan patọ ti awọn eniyan ti kii ṣe ọmọ orilẹede Benin Republic ma n gba lati fi ri iwe irinna ilẹ naa gba, ni lati fẹ ọmọ ilẹ naa,ki wọn si ṣe igbeyawo pẹlu rẹ.''

''Ọwọ sikun ofin tete ma n mu awọn to ba ṣe ayederu Passport ni Benin Republic nitori wọn kii ni ''National Identity Card'' ilẹ naa.

Oloye Toluwalaṣẹ ni awọn ti o ba ṣe ayederu iwe irinna ilẹ Benin Republic, asiri wọn ma n tete tu nitori nọmba idanimọ kaadi ilẹ naa, ti o yẹ ki wọn kọkọ ni, ki wọn to le ni iwe irinna, ko ni si.

Àkọlé fídíò,

Seyi Makinde: Ẹ̀yin tẹ́ fẹ́ fi ọ̀rọ̀ ẹ̀sin ba Oyo jẹ́, ẹ ṣọ́ra ṣe

Bakan naa lo fikun pe, iwe idanimọ yii ma n ni orukọ mọlẹbi bii mẹrin si marun un, ti yoo si jẹri si pe lootọ mọlẹbi awọn ni ẹni to ni iwe irinna naa pẹlu orukọ naa.''

''Ileẹjọ naa ni o si n ma n fi iwe pe ẹbi lati wa jẹri si pe wọn mọ ẹni to n beere fun iwe irinna naa.''

''Mi o le sọ pato iye ọdun ti o jẹ ijiya fun ẹni to ba ṣe ayederu iwe irinna ilẹ naa, amọ to ba jẹ Igboho gba iwe irinna nilẹ Benin, o seese ko fi ẹwọn jura o daju pẹlu gbogbo awọn ti wọn lọwọ ninu ṣiṣe ayederu naa, ko ba ṣe ọba alaye.''