Taraba: Emir ìlú Taraba ní bí àwọn Fulani Darandaran tilẹ̀ jẹ́ ẹ̀yà òun, wàhálà wọn ti pọ̀jù

Emir

Oríṣun àwòrán, Others

Emir ilu Muri nipinlẹ Taraba, Abbas Tafida ti fun awọn Fulani darandaran ni ọgbọn ọjọ lati kuro ninu igbo to wa ni ipinlẹ naa ki wọn to fi tipàtipa le wọn danu.

Emir naa lo kede gbendeke yii lasiko adura Eid ni ọjọ Iṣẹgun.

Eyi ko ṣẹyin bi ijinigbe, ipaniyan ati ikọlu ṣe peleke si nipinlẹ naa ti iwadii si fihan pe awọn ọdaran Fulani darandaran lo wa ni idi iṣẹlẹ naa.

Emir naa ni awọn Fulani darandaran lo wa nidi iwa ọdaran to n ṣẹlẹ ninu ilu naa, to si fun wọn ni ọgbọn ọjọ lati fi kuro ni awọn inu igbo abi ki wọn fi tipatipa le wọn jade.

O kesi awọn adari awọn Fulani darandaran yii lati ṣe afihan awọn ọbayejẹ to wa ninu wọn.

Àkọlé fídíò,

Ilorin Cripple Couple: Ọṣẹ ìfabọ́ ni tọkọ-taya tó ní ìpèníjà ẹsẹ̀ ń tà láti bọ́ ọmọ mẹ́ta

Emir naa ni: ''Nitori iṣekupani to n waye lojoojumọ nibẹ ni a ṣe fun awọn Fulani darandaran ni gbedeke lati kuro ni awọn inu igbo to wa ni ipinlẹ''

''O ti su wa, a kii ri oju orun lori ibẹru pe awọn darandaran yii le wa ṣe ikọlu si wa, bẹẹ ni ebi si n pa awọn araalu, lailai a ko le jẹ ki eleyii tẹsiwaju.''

Nibayii, awọn ẹgbẹ awọn Fulani darandaran, Myetti Allah ko i tii fesi si aṣẹ Emir naa.

Ipinlẹ Taraba to wa ni ila-oorun Ariwa orilẹede Naijiria ni ọpọlọpọ iṣẹlẹ ibi ti n waye to fi mọ ijinigbe, ipaniyan ati awọn iwa ọdaran miran ni agbegbe ọun.