Sunday Igboho: Ilé ẹjọ́ fi ìyàwó Igboho sílẹ̀ pé kò lẹ́jọ́ jẹ́ àmọ́ ìgbẹ́jọ́ ọkọ rẹ̀ ń tẹ̀síwájú lọ́jọ́ Aje

Oríṣun àwòrán, succo
Ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ lori igbesẹ lati fa Oloye Sunday Igboho le ijọba Naijiria lọwọ, ti sun igbẹjọ naa si ọjọ Aje ọsẹ to n bọ, iyẹn ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keje ọdun 2021.
Akọroyin BBC to wa niluu Cotonou jabọ pe, nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ni wọn bẹrẹ igbẹjọ ọhun, bo ti lẹ jẹ ọpọ awọn ololufẹ Igboho atawọn ajijagbara Yoruba Nation ti wa nile ẹjọ ọhun lati aarọ kutu.
O ni wọn ti fi iyawo Oloye Igboho silẹ lẹyin ti wọn ni awọn ko ri ẹsun kankan ka si lẹsẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Ẹni tó bá gba 'Passport Benin Republic' láì ṣe ọmọ onílùú, yóò fi ẹ̀wọ̀n jura"
- Bí mo ṣe jàjàbọ́ rè é lọ́wọ́ àwọn agbẹ́bọ̀n tó jà ọkọ̀ ìjà òfúrúfú mí bọ́ - Ọmọogun Abayomi Dairo sọ ìrírí rẹ̀
- Dubai se òjò àtọwọ́dá láti fi gbógun ti ooru tó mú jù
- Emir ìlú Taraba fún àwọn Fulani Darandaran ní gbèńdéke ọjọ́ 30 láti kúrò nínú igbó ìpínlẹ̀ òun
- To bá fẹ́ dara pọ̀ mọ́ Yoruba Nation, ìgbésẹ́ tó gbé rèé - Ilana Oodua
- Ìjọ́ mi kìí ṣe alágbé, kìí ṣe owó ló mú ká lé pásítọ̀ mọ́kànlélógójì - Oyedepo
Ti ẹ ko ba gbagbe, wọn mu Ropo, iyawo Oloye Igboho lọjọ kan naa ti wọn mu ọkọ rẹ ni papakọ ofururu kan nilu Cotonou, lasiko ti awọn mejeji ti n gbiyanju lati tẹkọ leti lọ si Germany.
Wayi o, wọn ti wa fi iyawo rẹ silẹ, ti wọn si ti jọwọ gbogbo iwe irinna atawọn dukia ti wọn gba lọwọ rẹ pada.
Rashidi Ladoja: Ẹ jẹ́ kí Bùhárí gbá'pòtí ìbò, bóyá yóò borí
Agbẹjọro Igboho ni ‘Passport’ Naijiria ati Germany ni wọn ka mọ Igboho lọwọ:
Agbẹjọro fun Oloye Sunday Igboho ni Benin Republic, Ibrahim David Salami sọ fun BBC pe, ijọba Benin ko ka iwe irinna silẹ okeere, Passport, tii ṣe ti orilẹ-ede Benin Republic mọ Igboho lọwọ, gẹgẹ bii awọn iroyin kan ṣe sọ ṣaaju.
O ni "Kii ṣe pe wọn ba iwe irinna silẹ okeere to jẹ ti orilẹ-ede Benin Republic lọwọ Oloye Igboho."
"Wọn ba iwe irinna ti Naijiria ati Germany lọwọ Igboho, nigba ti wọn ba ti orilẹ-ede Germany lọwọ iyawo rẹ."
Ẹwẹ, awọn agbofinro ti Igboho wa ni ikawọ wọn sọ pe igbeṣẹ awọn lati mu Igboho jẹ aṣẹ ti wọn gba lati ọdọ ijọba Naijiria.
Wayi o, ile ẹjọ giga to wa ni Cotonou ti wa ni ki wọn da oloye Igboho pada si agọ ọlọpaa ti wọn ti n sewadi iwa ọdaran, titi di ọjọ Aje ti igbẹjọ naa yoo tẹsiwaju.
Travelogue on Abeokuta: Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún yònbó ìbùdó àti èèyàn pàtàkí tó wà ní Abeokuta
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?
Wo ibi tí ọ̀rọ̀ dé dúró nílé ẹjọ́ ni Benin Republic lálẹ́ yìí
Oríṣun àwòrán, Others
Lẹ́yin o rẹ̀yin nile ẹ̀jọ́ ni Benin Republic ni wọ́n ti fẹnu ọ́rọ́ jona lale yii.
Adajọ́ sun igbẹ́jọ́ lori ọ́rọ́ Oloye Sunday Igboho si ọ̀jọ́ Aje to n bọ.
Agbejọ́rọ́ Oloye Sunday Adeyemo salaye pe asiko ko tii to lati sọ̀rọ̀ lori igbẹ́jọ́ naa sugbon oun gbagbọ́ pe didun lọ́san o so.
Agbejọ́rọ́ Ijọba naa ko ba awọ́n akọ́royin sọ́rọ̀.
Ere gbogbo di ọjọ Aje lori igbẹ́jọ́ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- To bá fẹ́ dara pọ̀ mọ́ Yoruba Nation, ìgbésẹ́ tó gbé rèé - Ilana Oodua
- Mo kìlọ̀ fún Igboho kó má wá sí ilé mi ní Benin Republic, lẹ́yìn táwọn ọlọ́pàá ń ṣọ́ mi - Alábàṣiṣẹ́pọ̀
- Ìjọ́ mi kìí ṣe alágbé, kìí ṣe owó ló mú ká lé pásítọ̀ mọ́kànlélógójì - Oyedepo
- Wo bí ìgbẹ́jọ́ Sunday Igboho yóò ṣe lọ ní ìlú Cotonou, Benin Republic lónìí