Sunday Igboho: Olayomi Koiki ní bíi bàbá ni Igboho jẹ́ sí òun, òun kò sì lè fi ṣe ẹlẹ́yà lásìkò tó wà nínú ìṣòro

Koiki and Igboho

Oríṣun àwòrán, Koiki Media

Agbẹnusọ fun Oloye Oloye Sunday Igboho, Olayomi Koiki ti ṣalaye pe, oun ko fi ajijagbara naa ṣe yẹyẹ lori awọn ohun to n la kọja lasiko yii, gẹgẹ bii iroyin ti awọn kan gbe kiri.

Koiki lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan to fi sita loju opo Facebook rẹ, nibi to ti ṣalaye lori ọrọ kan to sọ, ti awọn eeyan n pin kaakiri pe o n fi Igboho ṣe yẹyẹ.

Ninu atẹjade ọhun lo ti ṣalaye pe oun ko ṣe ẹlẹya Igboho nitori bii baba lo ṣe jẹ si oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni "O ti de eti igbọ mi pe fọnran ohun mi kan ti tan kalẹ lori ayelujara, nibi ti awọn eeyan kan ti sọ pe mo n ṣe ẹlẹya Oloye Igboho ṣugbọn bẹẹ kọ lọrọ ọhun ri."

"Bawo ni mo ṣe maa ṣe ẹlẹya ẹni to da bii baba fun mi? Bawo ni mo ṣe maa ṣe ẹlẹya ẹni to ko sinu wahala to wa lọwọ nitori ominira gbogbo wa?"

Oríṣun àwòrán, Olayomi Koiki

Koiki ṣalaye pe ohun oun lo wa ninu fọran naa lootọ, ṣugbọn kii ṣe pe oun n fi Igboho ṣe ẹlẹya, ṣugbọn idaro rẹ ni oun n ṣe."

O ni "Ninu fọnran naa, ara mi ko balẹ nitori inu ibanujẹ ni mo wa lasiko ọhun, ti mo si n wa ẹkun mu, eyii to da bi pe mo n rẹrin leti awọn eeyan kan."

Gẹgẹ bii ohun ti Koiki sọ, ẹnikan lo fi fọnran naa sita ninu ẹgbẹ ori ikansiraẹni kan ti awọn wa, ṣugbọn oun ko tii mọ ẹni naa.

Koiki pari ọrọ rẹ pe, oun ko fi Igboho ṣe yẹyẹ ri nigba kankan, oun ko si ni ṣe bẹẹ lailai.

Lẹyin naa lo ni ko ya oun lẹnu pe irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ waye, nitori awọn kọlọrọsi kan wa ti yoo gbiyanju lati mu oju awọn kuro lara afojusun ija ominira ti awọn n ja fun, eyii ti Igboho n jiya rẹ lọwọ.

Nnklan bii oṣu diẹ sẹyin ni Igboho kede Olayomi Koiki gẹgẹ bii agbẹnusọ rẹ, to si sọ pe ki gbogbo awọn ololufẹ oun gba ọrọ Koiki gẹgẹ bii ọrọ ti oun ba sọ.

Oríṣun àwòrán, Olayomi Koiki