Yoruba Nation: Ìgbẹ́jọ́ àwọn èèyàn méjìlá tí DSS kó nílé Sunday Igboho bẹ̀rẹ̀ lónìí

Yoruba Nation

Oríṣun àwòrán, Citizen TV

Igbẹjọ awọn eeyan mejila ti ajọ DSS fi sikun ofin mu nile Sunday Igboho lọjọ kinni oṣu Keje, ti bẹrẹ lonii l'Abuja.

Adajọ ile ẹjọ naa ti wa paṣẹ fun DSS lati ko awọn eeyan ọhun wa siwaju oun nile ẹjọ naa ni Ọjọbọ ọsẹ to n bọ, iyẹn ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Keje.

Ṣaaju ni ajọ DSS ti kọkọ fẹsun iwa ọdaran kan awọn eeyan naa lẹyin ti wọn fi sikun ofin mu wọn nile Oloye Sunday Igboho.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lasiko ti DSS n ṣafihan awọn eeyan ọhun lẹyin ti wọn mu wọn tan, DSS sọ pe awọn ka oriṣiriṣi ohun ija olori bii ibọn Ak-47, ọpọlọpọ ọta ibọn ati oogun abẹnu gọngọ mọ awọn afurasi ọhun lọwọ.

Lẹyin naa ni wọn kede pe awọn n wa olori wọn, iyẹn oloye Sunday Igboho, ti wọn si kede pe ko wa fara han nileeṣẹ awọn tabi ko foju wina ofin.

Àkọlé fídíò,

Travelogue on Abeokuta: Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún yònbó ìbùdó àti èèyàn pàtàkí tó wà ní Abeokuta

Eyii to mu ki Igboho sọ pe oun kii ṣe ọdaran, ati pe irọ ni DSS pa mọ oun lori awọn ohun ija ti wọn sọ pe awọn ri nile rẹ.

Ọjọ kinni, oṣu yii ni DSS kọlu ile Sunday Igboho loru ọganjọ, nibi ti wọn ti fi ṣikun ofin mu awọn ajijagbara Yoruba Nation mejila naa.

Lasiko ikọlu naa ni DSS ti ṣekupa eeyan meji, ti wọn si tun ba ọpọ dukia jẹ ṣugbọn Igboho bọ mọ wọn lọwọ.