IGP, police recruitment: Iléesẹ́ ọlọ́pàá kò gba ẹnikẹ́ni sísẹ́ lásìkò yìí- Usman Alkali Baba

Ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Twitter/Police

Irọ́ ni pé Iléesẹ́ Ọlọ́pàá ń gba àwọn èèyàn sísẹ́ lásìkò yìí- IGP Alkali

Oga agba ileesẹ ọlapaa ni Naijiria, IP Usman Alkali Baba ti kede pe kele a gbe awọn to wa nidi iroyin ofege to gbode kan pe ileese ọlọpaa n gbani sisẹ bayii.

Usman ni oun fi lede fun awọn eeyan Naijiria pe iroyin ofege ni iroyin igbanisiẹ naa.

Bakan naa lo salaye pe ki awọn ti isẹ ọlọpaa ba wu ni suuru diẹ sii.

Paapaa awọn to ti kopa ninu eto igbanisiẹ to waye ni ọdun 2020.

Àkọlé fídíò,

Sunday Igboho: Timi Orokoya ní orin Iléyá tí òun kọ lọ́dún 28 sẹ́yìn, ló padà wá ṣẹ báyìí

Oga agba gbaofinro ni Naijiria rọ awan eeyan ki wọn sọra ki wọn ma lọ ko sọwọ gbajuẹ.

Usman ni nigba ti eto igbanisisẹ ọlọpaa ba fẹ bẹrẹ, wọn yoo kọkọ fi atẹjade sita lati ileesẹ ọlọpaa ni pẹlu alaye bi o ti yẹ.