Nigerian Association of Resident Doctors: Ìyanṣẹ́lódí aláìlójọ́ bẹ̀rẹ̀ káàkiri Naijiria ní

Ileewosan nla UCH

Igba kẹrin ni yii ninu ọdun 2021 ti awọn dokita lorilẹede Naijiria kaakiri gunlẹ iyanṣelodi lati bere fun afikun owo oṣu wọn ni ọwọ ijba.

Awọn dokita to ba BBC sọrọ ni ijọba kuna lati risi eto igbaye gbadun awọn dokita ati ẹkọ to peye fun wọn.

Awọn dokita naa ni aibikita ijọba si ilakọja awọn dokita kaakiri n fa ifaṣẹyin fun eto ilera ni Naijiria.

Wọn ni ijọba kọ lati mu adehun ti wọn ṣe pẹlu wọn ṣe ni nkan bi osu mẹrin ṣẹyin ti wọn da wọ iyanṣelọdi duro nigba naa.

Kaakiri Naijiria, awọn dokita akẹkọmọṣẹ, Resident doctors lo poju ninu awọn dokita to n ṣiṣẹ ni Naijiria.

Ni ọpọ igba ni iyanṣelodi wọn ma n ni ipalara fun awn to nilo dokita, ti gbogbo ileewosan yoo si da paro-paro.

Àkọlé fídíò,

Esabod, Sunday Igboho: Kò burú bí Igboho ṣe wà lẹ́wọ̀n báyìí,ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí i ti aláboyún

Ìdí rè é tí a ó fi gùnlẹ̀ ìyanṣẹ́lódí aláìlójọ́ káàkiri Naijiria - Ẹgbẹ́ Dokítà

Ẹgbẹ awọn Dokita lorilẹede Naijiria, NARD ti sọ wi pe awọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi kaakiri orilẹede Naijiria bẹrẹ lati Ọjọ Aje, Ọjọ Keji, Oṣu Kẹjọ, 2021.

Aarẹ ẹgbẹ NARD, Dr. Okhuaihesuyi Uyilawa, lo kede rẹ ni ilu Umuahia to jẹ olu-ilu Abia lẹyin ipade gbogbo awọn igbimọ alakoso ẹgbẹ naa.

Dokita Uyilawa ninu ọrọ rẹ sọ idi ti awọn yoo fi gunle iyanṣelodi ọlọjọ gbọọrọ naa nitori ijọba apapọ kọ lati mu gbogbo ileri wọn ṣe.

O ni lati ọdun mẹwa ṣẹyin ni ẹgbẹ awọn dokita ti ni adehun pẹlu ijọba apapọ lori ọna ati mu idagbasoke ba eto ilera ni Naijiria, ti wọn ko si ri nkankan ṣe si titi di asiko yii.

Lara awọn idi ti wọn fi fẹ gunle iyanṣelodi naa re e;

  • Aisi agbegbe ati ileewosan to dara fun awọn araalu ati awọn dokita latio ṣiṣẹ
  • Aisi san owo osu awọn dokita loore-koore.
  • Ijọba apapọ kuna lati ma a san owo ijamba to jẹ ẹgbẹrun marun un to yẹ ki wọn ma a fun awọn dokita ni oṣooṣu lati ọdun 1991.
  • Ijọba kuna lati fi wọn si apo isuna ijọba ''personal payroll information systems'', ki owo osu wọn le ma a wọle deede.
Àkọlé fídíò,

Olagunsoye Oyinlola: Kí Olorun dáríjì wá lórí ọ̀rọ̀ yíi, a ti kùnà ìlérí wa fún ìran Yorùb

  • Ẹbi kan pere ninu ẹbi mọkandinlogun awọn dokita ti Coronavirus gbẹmi wọn lẹnu iṣẹ nikan lo ti ri owo ifẹyinti fun awọn oloogbe wọn gba.
  • Ijọba kọ lati dahun si gbogbo ipenija to n koju ẹka eto ilera lorilẹede Naijiria
Àkọlé fídíò,

Peter Fatomilola kìí ṣe agbódegbà Yahoo, Ó ń fẹ́ kí ìjọba, Òbí àti ilé ìjọsìn ṣe ohun tó y

  • Ida mẹrin aba iṣuna Naijiria nikan lo wa fun eto ilera nigba ti ida marundilọgbọn si aadọta lo wa fun owo oṣu awọn oṣelu ni Naijiria.
  • Ijọba ipinlẹ Eko yọ awọn ẹkọṣẹ dokita( Interns, Resident doctors) kuro ninu awọn ti ijọba yoo ma san owo oṣu fun un.

Ẹgbẹ awọn dokita ni Naijiria wa rọ tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ Naijiria ti iyanṣelodi naa yoo fa ipalara fun wọn.

Amọ wọn ni ijọba gbọdọ mu ileri wọn ṣe lori gbogbo adehun ti wọn ṣe pẹlu ẹgbẹ awọn dokita kaakiri orilẹede Naijiria.