Coronavirus Update: Àwọn àgùnbánirọ̀ 25 lùgbàdì àrún Coronavirus ní ìpàgọ̀ NYSC ní Gombe

NYSC

Oríṣun àwòrán, NYSC

Àkọlé àwòrán,

NYSC

O kere tan agunbanirọ mẹẹdọgbọn lo lugbadi aarun Coronavirus ni ipago awọn agunbanirọ NYSC to wa ni ipinlẹ Gombe.

Ninu atẹjade ti Kọmiṣọnna fun eto ilẹra nipinlẹ Gombe,Dr. Habu Dahiru fi lede lo ti sọ wi pe lasiko ayẹwọ ti awọn ṣe fun awọn agunbanirọ ni aarin ọjọ mẹta.

Dokita Dahiru ni gbogbo awọn ti ọrọ naa kan ni awọn ti ko lo si yara iyasọtọ ni ile iwosan Idris Mohammed infectious disease centre, Kwadon.

''Ninu awọn agunbanirọ to le ni ẹgbẹrun kan ti a ṣe ayẹwo aarun Coronavirus fun, awọn mẹẹdgbọn ninu wọn lo ni aarun naa, ti iya ọlọmọ si wa laarin wọn.''

''Bakan naa ni ipade pajawiri ti waye fun awọn oṣiṣẹ ile iwosan gbogboogbo, ti a si ti tẹlẹ awọn ilana to de fifi awọn eniyan si yara iyasọtọ.''

Àkọlé fídíò,

Gbajugbaja oṣere tiata, Bolaji Amusan fi hann wa bo se láyà to lori ètò ṣé o láyà.

Kọmisọnna ni: ''A si ti pese bi wọn yoo ṣe ma a jẹun, gba iwosan ati eto aabo to gbooro fun wọn nitori naa ko si ipaya.''

''Awọn ọlọpaa ti wa ni awọn yara iyasọtọ, ti wọn yoo si wa pẹlu wọn titi wọn yoo fi bori aarun Coronavirus naa, ti wọn yoo si da wọn pada lati lọ darapọ mọ awọn agunbanirọ to ku.''

Àkọlé fídíò,

Bethel Baptist high school Kaduna: Mi ò gbàgbọ́ pé ìjọba Naijiria ń ṣe ojúṣe rẹ̀ lórí ètò

''Bakan naa ni awọn dokita nipa ihuwasi ọmọniyan yoo wa nibẹ lati ran wọn lọwọ nitori awọn miran wa nibẹ ti ko fi ami kankan han, amọ ti wọn ko mọ nipa aarun naa.''

Àkọlé fídíò,

Olagunsoye Oyinlola: Kí Olorun dáríjì wá lórí ọ̀rọ̀ yíi, a ti kùnà ìlérí wa fún ìran Yorùb

''Nitori naa idanilẹkọ nlọ lọwọ fun wọn ki wọn le mọ wi pe o ṣoro fun wọn lati darapọ mọ awọn eniyan lawujọ ti wọn ba ti lugbadi aarun Coronavirus''

Oríṣun àwòrán, Nysc

Kọmiṣọnna fun eto ilẹra nipinlẹ Gombe,Dr. Habu Dahiru ni ki awọn eniyan tẹlẹ ilana to de itankalẹ aarun Coronavirus, nitori aarun naa ṣi n ja ranyin nilẹ.

Dokita Dahiru ni awọn yoo kan si awọn ipinlẹ ti wọn ti wa ati ijọba ibilẹ wọn, ki awọn eleto aabo le tọpaṣẹ awọn ti wọn tan mọ mọ fun ayẹwo aarun Coronavirus.

Àkọlé fídíò,

Peter Fatomilola kìí ṣe agbódegbà Yahoo, Ó ń fẹ́ kí ìjọba, Òbí àti ilé ìjọsìn ṣe ohun tó y