Hushpuppi news today: Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́nu mẹ́rin ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ìwádìí àjọṣepọ̀ Abba Kyari àti Ramoni Igbalode

Abba Kyari ati Hushpuppi

Oríṣun àwòrán, Daily Nigerian

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti kede pe iṣẹ ti bẹ̀rẹ̀ lori iwadii ajọṣepọ Hushpuppi ati Abba Kyari.

Wọn ni igbimọ ẹlẹnu mẹrin naa ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ iwadii lori ohun to pa Ramoni Igbalode pọ mọ Abba Kyari.

Police Service Commission ni pe Abba Kyari ti lọ rọọkun nile bayii.

Ogbeni Ikechukwu Ani to jẹ adari ẹka eto ifitonileti wọn ni pe Abba Kyari ti lọ rọọkun nile ati pe iṣẹ iwadii ti bẹrẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti yọ igbakeji kọmiṣọna ọlọpaa, Abba Kyari nipo titi ti iwadii yoo fi pari lori ẹsun ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ FBI fi kan.

Igbesẹ yii lo waye lẹyin ti ọga agba ileeṣẹ naa ni Naijiria, Baba Usman Alkali sọ pe ki wọn ṣe bẹẹ.

Àkọlé fídíò,

Bethel Baptist high school Kaduna: Mi ò gbàgbọ́ pé ìjọba Naijiria ń ṣe ojúṣe rẹ̀ lórí ètò

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Naijiria ti yọ Abba Kyari nípò nítórí ẹ̀sùń tí US fi kàn án

Wọ́n ní kí Kyari máá lọ ilé títí tí ìwádìí yóò fi parí lórí ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Hushpuppi

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn ọlọpaa ni Naijiria, Nigeria Police Service Commision, fi lede, eyii ti agbẹnusọ rẹ, Ikechukwu Ani buwọlu, o ni ileeṣẹ naa ti pinnu pe ki Kyari lọ joko sile titi di igba ti iwadii yoo pari lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Ṣaaju akoko yii ni ọpọ awọn ọmọ Naijiri to kọkọ n gboriyin fun Kyari, lori akitiyan rẹ lati kapa iwa ọdaran lawujọ.

Ṣugbọn ajọ ọyẹlẹmuyẹ ilẹ Amẹrika fẹsun kan pe o n ba gbajumọ onijibiti ori ayelujara, Hushpuppi dowo pọ.

Hushpuppi n jẹjọ nilẹ Amẹrika lori ẹsun pe o lu awọn eeyan kan ni jibiti, o si ti jẹwọ pe lootọ ni oun ṣe ohun ti wọn fẹsun rẹ kan oun.

Iwadii FBI fi han pe Hushpuppi fi owo ranṣẹ si Kyari, ko le lo ipo rẹ gẹgẹ ọlọpaa lati fi orogun Hushpuppi nidi iṣẹ gbajuẹ si atimọle.

Àkọlé fídíò,

Bí ìjọba bá kọ̀ tí kò ṣèdájọ́, tí Ọlọ́pàá kọ̀ pé àwọn kọ́ ló paá, ẹni tó pa ọmọ mi, náà máa ...

Awọn atẹjade ka lati ile ẹjọ ilẹ Amẹrika fi han pe iye owo ti Hushpuppi ti fio ọna ẹburu gba lọwọ awọn eeyan ti le ni milliọnu mẹtalelogun dọla.

Ẹwẹ, Kyari ti sọ pe oun ko mọ ohunkohun nipa ẹsun ti wọn fi kan oun.

Wayi, ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo n woye irufẹ igbesẹ ti ijọba naijiria yoo gbe lori ọrọ naa, boya wọn yoo fa le ijọba Amẹrika lọwọ ni tabi wọn ko ni ṣe bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Others

Ki lo tin ṣẹlẹ sẹyin?

Ọ̀gá ọlọ́pàá Naijiria sọ pé kí wọ́n yọ Abba Kyari nípò nítórí ẹ̀sùń tí US fi kàn án

Ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Usman Alkali Baba ti sọ wi pe ki wọn yọ igbakeji kọmiṣọnna ọlọpaa nipo, Abba Kyari nipo ni kiakia, ti iwadii yoo fi pari lori ẹsun ti orilẹede Amẹrika fi kan an.

Alkali fi imọran naa lede ninu lẹta to fi ṣọwọ si Ajọ to n risi ọrọ ileeṣẹ awọn ọlọpaa ni Ọjọ kọkanlelọgbọn, Osu Keje, ọdun 2021.

Àkọlé fídíò,

Okunade Sijuwade: Ìfẹ́ tí Sarun tó súnmọ́ Ooni jù láyé ní sí í ló sọ ọ́ di abọ́bakú- Adeye

Ẹsun ti orilẹede Amẹrika fi kan Abba Kyari ni pe o mọ nipa iwa jibiti ti Hushpuppi hu, ati bi o ṣe gba biliọnu kan dọla lọwọ oniṣowo kan ni orilẹede Qatar.

Kyari ti sọ wi pe oun ko jẹbi ẹsun kankan ti wọn fi kan oun nitori oun ko ni ibaṣepọ pẹlu Hushpuppi abi oniṣowo kankan ni Qatari.

Àkọlé fídíò,

Gbajugbaja oṣere tiata, Bolaji Amusan fi hann wa bo se láyà to lori ètò ṣé o láyà.

Amọ, Ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria ninu lẹta to fi ṣọwọ si Ajọ Police Service Commision naa ni yiyọ Kyari ni ipo fun igba ti iwadii yoo fi pari ni ọna to ba ofin ileeṣẹ naa mu.

Alkali ni: ''Dida Abba Kyari duro yoo gba Ajọ naa laye lati ṣewadii ẹsun to lagbara ti wọn fi kan an lai ni ilara tabi abuku ni inu.''

''Amọ, dida Kyari duro lẹnu iṣẹ ko sọ wi pe ati ni o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.''

Bakan naa ni ikọ naa ti gbe igbimọ-ẹlẹni mẹrin dide lati ṣewadii ẹsun ti ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lati orilẹede Amẹrika, FBI fi kan an.

Àkọlé fídíò,

Peter Fatomilola kìí ṣe agbódegbà Yahoo, Ó ń fẹ́ kí ìjọba, Òbí àti ilé ìjọsìn ṣe ohun tó y

O fikun pe igbimọ naa yoo ṣewadii finifini awọn iwe ẹsun ti wọn fi kan an, lati le fi idi otitọ mulẹ lori iṣẹlẹ naa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Frank Mba ni DIG Joseph Egbunike ni yoo dari igbimọ ẹlẹnimẹrin naa.