Radio Nigeria attack: Àwọn jàndùkú ba ọ̀kẹ́ àìmoye dúkìá jẹ́ lásìkò ìkọlù sí Amuludun FM n'Ibadan

AMuludun FM, Ibadan

Oríṣun àwòrán, AMULUDUN FM

Awọn janduku kan ti ya bo ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ Radio Nigeria to wa niluu Ibadan, ti wọn si ba ọpọ dukia jẹ nibẹ.

Iroyin ni awọn janduku naa ti wọn to bii mejila ya bo ileeṣẹ naa ti ọpọ mọ si Amuludun 99.1FM ni nnkan bii aago mejila ọsan ọjọ Abamẹta.

Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa sọ fun BBC Yoruba pe ọpọ dukia ti iye rẹ ko din ni ọpọ miliọnu naira ni awọn janduku ọhun bajẹ lasiko ikọlu naa.

Lara awọn ohun ti wọn bajẹ ni awọn irinṣẹ ti wọn n lo ni ọọfisi, awọn ferese ọọfisi, to fi mọ awọn ọkọ ayọkẹlẹ atawọn dukia miran.

Ọga agba ileeṣẹ naa, Niyi Dahunsi ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun awọn akọroyin.

Dahunsi ṣalaye pe awọn ti fi isẹlẹ naa to awọn agbofinro leti, wọn si ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.

Àkọlé fídíò,

Bethel Baptist high school Kaduna: Mi ò gbàgbọ́ pé ìjọba Naijiria ń ṣe ojúṣe rẹ̀ lórí ètò

O ni "Oootọ ni ni awọn eeyan kan kọlu ọọfisi wa."

"Awọn oṣiṣẹ ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS, ọlọpaa ati NSCDC ti sọ pe awọn yoo bẹrẹ iṣẹ lori ikọlu naa ni kankan."

Iṣẹlẹ yii lo n waye lẹyin ọjọ diẹ ti awọn janduku kan kọlu ile itaja igbalode Palms Mall to wa lagbegbe Ring Road, niluu Ibadan, nibi ti ẹmi eeyan kan ti sọnu.

Titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ, ko sẹni to tii le sọ eredi ikọlu ọhun.

Àkọlé fídíò,

Gbajugbaja oṣere tiata, Bolaji Amusan fi hann wa bo se láyà to lori ètò ṣé o láyà.