Afghanistan crisis: Dele Farotimi ní àwọn agbésùnmọ̀mí le gbàjọba Nàíjíríà tí ìjọba kò bá jáwọ́ nínú ojúṣàájú àti ẹlẹ́yàmẹ̀yà

Agbẹjọro kan, to tun jẹ ajafẹtọ ọmọniyan, Dele Farotimi ti sọ pe o ṣeeṣe ki awọn ọmọ ẹgbẹ agbesumọmi gbajọba ni Naijiria gẹgẹ bii ẹgbẹgun ọlọtẹ Taliban ṣe gbajọba ni Afganistan.
Farotimi lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.
O ni ijọba Naijiria ko sa ipa rẹ to bo ṣe yẹ lati kapa awọn jaduku, awọn ọdaran Fulani darandaran atawọn ajinigbe.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Fadá wọ gàù torí pé ó 'kiss' akẹ́kọ̀ọ́bìnrin mẹ́ta lọ́jọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́jáde
- Ìpàdé ikọ̀ Amotekun pẹ̀lú àwọn aládúgbò ọmọ ọdún 15 tí wọ́n yìnbọn pa ní Mokola, ohun tí a gbọ́ níbẹ̀ nìyí
- Gómìnà ìpínlẹ̀ kan rèé tó ní kí aráàlú ó lọ ra ìbọn láti dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ àwọn agbébọn
- Èyí lohun tí Amòfin àgbà Nàìjíríà, Malami sọ níléẹjọ́ lónìí nípa àjọṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lu Fulani àti ìkọlù tó wáyé nílé Igboho
- Àlàyé rèé lórí nkan tó pa èèyàn méje nínú ẹbí kan ní ìpínlẹ̀ Osun
- Oní Típà tó bá ta yanrìn ní iye owó tí a kò fọwọ́ sí yóò fojú balé ẹjọ́ - Ijọba ìpínlẹ̀ Ondo
- Wo ohun tó fẹ́ mú kí àwọn aṣòfin Ogun fi ọlọ́pàá mú 'ọba aládé' kan ní Ijebu
Agbẹjọro ọhun ṣalaye siwaju pe ko si iyatọ kankan ninu ohun ti awọn Taliban n ṣe ni Afganistan ati ohun ti awọn ijọba ipinlẹ kan n ṣe ni Naijiria.
O ni "Ki ni Taliban fẹ ṣe ni Afganistan to yatọ si ohun ti Ganduje n ṣe ni Kano?"
"Koda, awọn mii gan nilẹ Yoruba n dunnu lori ohun to ṣelẹ ni Afganistan nitori pe ẹsin kan nii awọn atawọn ọmọ ogun Taliban ṣe."
Oba Ogboni Abalaye n fẹ́ kí wọ́n o má a fi ẹ̀sìn àbáláyé búra fún àwọn olóṣèlé Naijiria
Farotimi tẹsiwaju pe iwa ti ijọba Najiria n wu fẹẹ buru ju eyii ti awọn Taliban n wu lọ ni Afgnistan lọ."
O ṣalaye pe "Ohun to n ṣẹlẹ ni Naijiria lọwọ yii ti n sunmọ eyii to ṣẹlẹ ni iru awọn ilu bii Kigali, Mogadisu ati bẹẹ lọ ti a ba ko ba tete fa ọwọ ọmọ wa s'akọ."
"Itajẹsilẹ to n waye ni Naijiria ti n kọja irufẹ awọn ifẹmiṣofo to ṣẹlẹ lawọn ilu wọnyii, ki ni a wa fi yatọ si Afganistan?
O ni ti naijiria ba kọ lati pada si ẹsẹ aarọ ti ko si jawọ ninu ẹlẹyamẹya, igbẹyin rẹ yoo buru ju ti Afganistan lọ.
Bo tilẹ jẹ pe Farotimi ni oun ko faramọ ki Naijiria pin, ṣugbọn ti nnkan ba n lọ bo ṣe n lọ yii, o ṣeeṣe ko jẹ pe Aarẹ Muhammadu Buhari ni yoo jẹ Aarẹ ikẹyin ni Naijiria gẹgẹ bii orilẹ-ede.
O pari ọrọ rẹ pe "Ibi ti ko ba ti si ootọ ati idajọ ododo, ko ni si ifọkanbalẹ nibẹ."
"Iyẹn ni pe ti a ko ba pada si ẹsẹ aarọ ni Naijiria, omi yoo tẹyin wọ igbin Naijiria lẹnu."
Yollywood movies: Gbajúmọ̀ òṣèré, Rose Odika ní aráàú, àjọ 'Censors board'