Akku Yadav Rape: Okùnrin tó bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin lòpọ̀ gba ìdájọ́ gbígbóná nílé ẹjọ́

Akku Yadav

Oríṣun àwòrán, factrepublic

Oniruru iwa ọdaran ni awọn okunrin kan maa n wu si awọn obinrin ti wọn a si maa jiya ẹṣẹ naa lọwọ obinrin bẹẹ tabi lọdọ ijọba, bii ki wọn ri ẹwọn he.

Lara awọn iwa aburu ninu ile ti awọn okunrin si maa n wu si awọn obinrin ni bii lilu ni ilu bara tabi ifipabanilopọ, to jẹ eyii to buru julọ.

Lọpọ igba ni awọn obinrin maa n ṣekupa awọn okunrin to bá ba wọn lopọ lai duro de idajọ ile ẹjọ, eyii to ti yọsi si iku ojiji ọpọ okunrin bẹẹ.

Lara awọn okunrin ti ẹmi wọn ti bọ sọnu lọwọ awọn obinri ti wọn ba lopọ ni Akku Yadav to n gbe lagbegbe Nagpur ni India.

Lati igba ti okunrin naa ti wa ni ọmọ ọdun mejila lo ti maa n fipa wọ awọn ọmọ adugbo lọ sinu kọrọ lati fi ipa ba wọn lopọ, toun tawọn ọrẹ rẹ.

Iwa naa buru to bẹ ti nnkan bii ẹbi marundinlọgbọn fi adugbo naa silẹ.

Awọn obi ti wọn ko lagbara lati ko kuro ni adugbo, wọn lọ yọ awọn ọmọbinri wọn kuro nile ẹkọ, ti wọn si ti awọn ọmọ na mọ inu yara lọna ati dena ifipanilopọ to le ṣẹlẹ si wọn..

Iroyin ni awọn obinrin bẹru Yadav to bẹẹ ti awọn to n ta ẹfọ kii ya si ọna adugbo rẹ eyii to fa ọwọngogo ẹfọ ladugbo ọhun.

Awọn iwa ipa mii ti Yadav n wu

Yatọ si ifipabalipọ, Yadav tun maa n fi ipa gba owo lọwọ awọn obinrin, ti yoo si ṣekupa ẹyilkeyi ninu wọn to ba yari.

Iwa alọnilọwọgba yii ni Yadav fi n ṣe iṣẹ ṣe ti ọpọ awọn to maa n gba owo lọwọ wọn si jẹ awọn oniṣowo kekeke atawọn to mọ pe wọn ko lagbara lati kọ si oun lẹnu.

Fun nnkan bii ọdun mẹtala o le ni Yadav fi maa n fi ipa ba awọn obinrin lopọ ti wọn ki si le ke gbajare nitori pe o maa n dukoko mọ wọn pẹlu ifipabanilopọ mii.

Ko din ni ogoji obinrin to ba lọpo lagbegbe kan laarin ọdun mẹwaa sira wọn, ti ẹni to kere julọ lara awọn obinrin naa si jẹ ọmọ ọdun mẹwaa pere.

Lara awọn awọn ti Yadav ṣe baṣubaṣu ni obinrin ti o ba lopọ fun ọpọ wakati lẹyin to ti kọkọ gun ọkọ obinrin naa lọbẹ ni itan.

O tun fipa ba obinrin miran lopọ lẹyin ọjọ mẹwaa to bi ọmọ tan.

Itiju naa pọ fun ọbinrin ọhun to bẹẹ to fi lọ pokun so.

Iwa miran to buru jai ti Yadav tun wu ni igba to ya aṣọ mọ aboyun oṣu meje lara ni ita gbangba, to si fi ipa ba lo pọ.

Nibo ni awọn agbofinro wa ni gbogbo ako ko yii?

Gẹgẹ bii iroyin ṣe sọ, awọn ọlọpaa mọ si gbogbo iwa aburu ti Yadav n wu yii.

Ẹni ọdun mejilelọgbọna naa n yan fanda laarin ilu ni, nitori pe o ti fi owo di awọn ọlọpaa lẹnu.

Bo tilẹ jẹ pe awọn obinrin ti Yadav n fipa ba lopọ n fi ọrọ na to ọlọpaa leti, ni ṣe ni awọn ọlọpaa n di ẹbi ọrọ na ru awọn obinrin ọhun.

Awọn ọlọpaa ko ṣe ohunlohun nipa awọn iwa ti ọkunrin na n wu niwọn igba to jẹ pe ko fọwọ kan ọmọ tabi obinrin awọn alẹnulọrọ laarin ilu.

Nigba to ya, Yadav atawọn ẹmẹwa rẹ gbiyanju lati fipa ba obinrin kan ti orukẹ rẹ n jẹ Usha Narayane lopọ, ṣugbọn o kọja lẹyin to ni oun yoo dana sun ara oun ati Dadav, to fi mọ awọn ẹmẹwa rẹ naa.

Ni kete ti awọn abinrin agbege naa gbọ ohun ti obinrin ọhun ṣe, wọn gbimọ pọ lati gbẹsan lara Yadav, eyii to mu ko gba agọ ọlọpaa lọ fun abo ara rẹ, nibi to ti dero atimọle.

Igbẹyin Yadav

Ni ikẹyin, Yadav foju bale ẹjọ, ṣugbọn awọn obinrin to ti fipa balopọ ni ó pé awọn ki awọn ṣẹwọn ju ki wọn tu afurasi naa silẹ lọ, eyii to mu ki awọn obinrin naa, ti iye wọn jẹ igba lọ silẹ ẹjọ ti wọn ti n gbọ ẹjọ rẹ pẹlu ọbẹ lọwọ wọn.

Lọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ, ọdun 2014, Yadav ri ọkan lara awọn obinrin to ti balopọ nile ẹjọ, o si pe obinrin naa ni oninabi, ati pe oun yoo tun fipa ba lopọ lẹẹkan sii.

Ọrọ naa bi obinrin ọhun ninu to bẹẹ to fi ju bata lu olujẹjọ ọhun, iyẹn Yadav, awọn obinrin akẹgbẹ rẹ si ṣe bẹẹ pẹlu.

Kato wi, ka to fọ, wọn ti bẹrẹ si n gun yadav lọbẹ lẹyin ti awọn ọlọpaa fẹsẹ fẹ tan niroti idarudapọ to waye nile ẹjọ ọhun.

Ni ikẹyin, wọn gun Yadav lọbẹ nigba marundinlọgọrin (75), wọn tun ge nnkan ọmọkunrin rẹ sọnu gẹgẹ bii ẹsan iwa ifipabanilopọ rẹ.

Ọlọpaa fi ṣikun ofin mu marun un lara awọn obinrin naa ṣugbọn wọn gba itusilẹ lẹyinorẹyin, kò sì sí ọkankan ninu wọn to foju bale ẹjọ lori igbesẹ ti wọn gbe ọhun.