Kaduna LG Polls: Bí àṣìta ìbọn ṣe pa ọmọ ọdún 9 níbi ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ ní Kaduna

Oríṣun àwòrán, Cable
Àṣìtà ìbọn láti ọwọ́ ọmọogun kan lo pa ọmọ ọdún mẹ́sàn kan ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Zainab Bala-Umar ni wọ́ọ̀dù Gwanki níjọba ìbílẹ̀ Makarfi ní ìpińlẹ̀ Kaduna lásìkò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tó wáye lọ́jọ́ sátidé.
Ẹni tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú rẹ̀ ṣàlàyé fún ìwé ìròyìn Daily Trust pé sójà kan lo yìnbọn lásìkò tó n gbìyànjú láti tú àwọn èrò tó péjọ ká.
Ó ní ọ̀kàn nínú àwọn olùdíjè sípò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) pé sójà náà wá síbi ìdìbò ọ̀hún.
- Kà nípa ìtàn okùnrin tí obìnrin 200 gún lọ́bẹ pa, tí wọ́n sì tún gé nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ sọnù
- Ògo ilé wá wọlẹ̀ lójijì! àwọn darandaran ajínigbé pa abúrò mí! - Ọmọyẹle Ṣowore
- Àwọn nǹkan tí a mọ̀ nípa gbas-gbos tó n wáyé láàrín Nedu Wazobia àti ìyàwó rẹ̀ tẹ́lẹ̀
- Á ṣiṣẹ́ tako Seyi Makinde fún sáà kejì - Igun PDP l‘Oyo fọnmú
" Maiyere lo pe sójà wá, ti ó sì yìnbọn sí òkè, ọta ìbọn náà ló bá ọmọ kékere náà ó sì kú"
Ẹ̀wẹ̀, agbẹnusọ ọlọ́pàá ní ìpińlẹ̀ Kaduna ASP Mohmmed Jalige sọ pé wọn kò gbà awọn ọmọogun láàyè láti péjú síbi ti ìdìbò tí n wáyé.
Ó ní ọlọ́pàá yóò mú afurasí náà, ìwádìí yóò wáyé, lẹ́yìn náà ni yóò jábọ̀ fún àwọn oníròyìn.
Ẹ̀wẹ̀, ìròyìn sọ pé gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna , Nasir El-Rufai fìdírẹmi ni ìdí àpótí rẹ̀ tó jẹ́ 01, ni agbègbè Ungwan Sarki ni Kaduna North ìpińlẹ̀ náà.
Gẹ́gẹ́ bí alábojútó ìbò agbègbè rẹ̀ Muhammed Sanni ṣe jábọ̀ ni pé ènìyàn mọ́kàndínlọ́gọ́jọ ló dìbò, sùgbọ́n ènìyàn méjìlélọ́gọ́ta ló dìbò fún APC gẹ́gẹ́ bí alága.
Sáájú ni gómìnà tí ni òun ni ìgbàgbọ́ nínú ètò ìdìbò Nàìjíríà, àti pé kí gbogbo ènìyàn faramọ́ àbájáde ètò ìdìbò náà nítórí pé yóò nira láti ṣe mágàmágò ìbò níbẹ̀.
El-Rufai ni lílo maásìnì ìgbàlódé fún ètò ìdíbò jẹ̀ ìtẹ̀síwáju jú èyí tí wọ́n ṣe ní ọdún 2018 lọ, níbi ti ẹlòmíràn ti dìbò ju ìgbàkan lọ