Attack On Kabba Custodial Centre: Kódà, gbogbo ẹlẹ́wọ̀n tó kù tó sá lọ ni ọwọ́ wa máa tẹ̀ láìpẹ́- Aregbesola

Aregbesola

Oríṣun àwòrán, @Aregbesola

Saaju ni iroyin naa ti se awọn eniyan Naijiria ni kayeefi bi awọn agbebon ṣe ya bo ọgba ẹwọn to wa ni Kabba ni ipinlẹ Kogi.

Ariwo nibo ni eto aabo Naijiria n lọ bayii ni gbogbo eeyan n pa.

Minisita feto abẹlẹ lorileede Naijiria ni igbesẹ ti n lọ lọwọ lati rii pe awọn mu awọn agbebọn to kọlu ọgba ẹwọn to wa ni ilu Kaba ni ipinlẹ Kogi.

O ni yatọ si awọn ẹlẹwọn to sa, awọn agbofinro n tọ pinpin awọn agbebọn to wa nidi ikọlu naa.

O kere tan ẹlẹwọn ojilerugba lo sa mọ awọn alasẹ lọwọ ni ọgba ẹlẹwọn Medium Security Custodial Centre (MSCC) to wa ni Kabba ni ipinlẹ Kogi.

Òhun gbogbo tí padà sípò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Kabba - Aregbesola

Aregbesola lawọn ti n gbe igbesẹ lati mu awọn agbebọn

Alukoro ileeṣẹ ọgba ẹwọn naa arakunrin Francis Enobor fidi iṣẹlẹ yi mulẹ ninu atẹjade kan lọjọ Aje to si ni nkan bo ago mejila oru ni ikọlu naa waye.

Minisista Aregbesọla sọ pe awọn ti ṣe agbende ikọ kogberegbe lati mu awọn ẹlẹwọn to sa yi nigba ti ikọ alapapọ awọn agbofinro si ti n tọ ipasẹ awọn agbebọn to ṣigun ba ọgba ẹwọn.

Àkọlé fídíò,

Ọ̀gá Bello: Àìgbọ́n ló ń da àwọn òsèré tíátà tó ń jà lórí ayélujára láàmú

O ni ki araalu ma foya nitori awọn ba gbogbo eto lọ bo ti ṣe yẹ ati pe awọn agbofinro Naijiria yoo mu awọn agbebọn wọn yi.

"Gbogbo igbesẹ to yẹ la o gbe lati dawọn pada si ọgba ẹwọn.A ti sọ fun awọn ileeṣẹ ọlọpaa agbaye INTERPOL nipa awọn to sa lẹwọn yi ki wọn ba le mu eyikeyi to ba sa de ọdọ wọn kuro ni Naijiria''

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ninu ikọlu to waye, oṣiṣẹ ọgba ẹwọn naa meji kan ni wọn ko mọ ibi ti wọn wa nigba ti ọlọpaa kan ati ọmọ ogun kan si ba iṣẹlẹ naa lọ.

Ẹlẹwọn ọọdunrun din mẹfa lo wa ni ọgba naa nigba ti ikọlu yi fi waye.

Àkọlé fídíò,

Adene Oluwabukola Deborah: Bàbá mi kò kọ́kọ́ fọwọ́ sí iṣẹ́ ìlù lílù ṣùgbọ́n....

Pupọ ninu wọn ribi salọ nigba ti awọn agbebọn fi ado ibugbamu lu ogiri ẹwọn naa.

Amọ ṣa Minisita ni o ṣẹku ẹlẹwọn mejidinlọgbọn ti ko ribi salọ.

Àkọlé fídíò,

Yoruba Nation: Kò sí ìdí tí à ó fi bínú sí Akeredolu lórí ọ̀rọ̀ Yorùbá Nation

O ni awọn mi ti jọwọ ara wọn ti wọn si pada si ọgba ẹwọn naa.

Iwadii fi han pe ojilenigba (240) ẹlẹwọn lo salọ lasiko ti awọn agbebọn naa kọlu ọgba ẹwọn ọhun.

Ọga agba ileeṣẹ to n ri si ọrọ ọgba ẹwọn ni Naijiria ti paṣẹ pe ki wọn bẹrẹ iwadii lori ohun to ṣokunfa ikọlu naa.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, iṣẹlẹ naa waye loru ọjọ kejila, oṣu Kẹsan an, ọdun yii nigba ti awọn agbebọn naa ya bo ọgba ẹwọn naa ti wọn si ṣina ibọn bolẹ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọgba ẹwọn ni ipinlẹ Kogi, Francis Enobore ni awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati ṣawari awọn ẹlẹwọn to salọ lasiko ikọlu ọhun.

Ọga agba ileeṣẹ to n ri si ọrọ ọgba ẹwọn, Haliru Nababa ti lọ ṣabẹwo si ọgba ẹwọn naa lati wo bi nnkanṣe ri nibẹ.

Àkọlé fídíò,

Femi Falana: Mẹ̀kúnnù gbọ́dọ̀ ṣetán láti gba ẹ̀tọ́ wọn, ìjọba ti kùnà lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn

Lẹyin na lo ke si awọn araalu lati ta awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa lolobo ti wọn ba kofori ẹnikẹni lara awọn ẹlẹwọn ọhun.

Ọdun 2008 ni wọn gbe ọgba ẹwọn naa kalẹ, iye ero ti wọn ṣeto rẹ fun si jẹ igba.

Ọ̀ọ́dúnrún dín mẹfa (294)eeyan lo wa ninu ọgba ẹwọn naa lasiko ikọlu ọhun, okòólénígba àti mẹ́rìn (224) lara ṣi n jẹjọ lọwọ, nigba ti aadọrin ti gba idajọ.