Sunday Igboho: Olajengbesi ní iléẹjọ́ níkan ló le kéde pé òun ń wá ọmọ Nàíjíríà kankan

DSS ati Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Others

Ọkan lara awọn agbẹjọro fun Oloye Sunday Igboho, Pelumi Olajengbesi ti ni Ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ati Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, EFCC, ko ni aṣẹ labẹ ofin lati kede ''Mo n wa ọ fun ọmọ Naijiria kankan'' lai gba aṣẹ ileẹjọ.

Olajengbesi sọ eyi ninu atẹjade to fi lede fun awọn oniroyin eyi ti ko ṣẹyin bi ajọ DSS ṣe kede pe wọn n wa Sunday Igboho.

Ẹsun ti DSS fi kan Igboho ni pe o n ko ohun ijagun pamọ lati da omi alaafia orilẹede Naijiria ru, eleyii ti Igboho ni oun ko jẹbi ẹsun naa.

Igboho si ti wa ni ahamọ ni orilẹede Benin Republic lati Ọjọ Kọkandinlogun, Osu Kẹjọ, ọdun 2021 lẹyin ti ajọ DSS ṣe ikọlu si ile rẹ to wa ni ilu Ibadan.

Meji lara awọn alabaṣiṣẹ Sunday Igboho ni awọn oṣiṣẹ ajọ DSS naa pa, ti wọn si fi awọn mejila si atimọle.

Àkọlé fídíò,

Yoruba Nation: Kò sí ìdí tí à ó fi bínú sí Akeredolu lórí ọ̀rọ̀ Yorùbá Nation

Amọ lẹyin ọgọta ọjọ, DSS fi awọn mẹwaa silẹ ninu wọn, ti wọn si kọ lati jọwọ awọn meji lẹyin ti wọn gba aṣẹ ijọba.

Bakan naa laipẹ yii ajọ EFCC kede pe wọn n wa arakunrin Adewale Jayeoba kan to jẹ adari ẹka kara-kata ni ileeṣẹ Wales Kingdom Capital Limited, fun iwa ajẹbanu to fẹrẹ to ẹgbẹrun miliọnu naira, N935m.

Nigba ti agbẹjọro Sunday Igboho n fesi si iṣẹlẹ yii, o ni ati DSS ati EFCC ko si ẹni to gba aṣẹ ni ileẹjọ ki wọn to kede pe wọn n wa Sunday Igboho ati Jayeoba.

''Igbeṣẹ awọn ẹṣọ alaabo ni Naijiria lati ma a dede kede pe wọn n wa awọn ọmọ Naijiria kan ko ba ofin mu rara nitori wọn ko gba aṣẹ ijọba.''

''Abẹ iṣejọba ologun nikan ni wọn ti n ṣe iru rẹ nitori wọn kọ ẹyin si ofin ilu, eleyii ti awọn ajọ ọtẹlẹmuyẹ n ṣe lọwọlọwọ ni Naijiria''

''Ko si ofin ni Naijiria to fun DSS tabi EFCC ni agbara lati kede pe wọn n wa ẹnikẹni lai gba aṣẹ ijọba.''

Àkọlé fídíò,

Hijab Female Footballer: Zulfah ní àlá òun ní láti jẹ́ agbábọ́ọ̀lù obìnrin tó dáńtọ́

''Ofin to de iwa ọdaran, The Administration of Criminal Justice Act, 2015 to de gbogbo awọn ajọ ọtẹlẹmuyẹ ti ijọba apapọ fihan gbangba ilana ti wọn gbọdọ gba lati fi ọmọ Naijiria kankan jofin ẹsun iwa ibajẹ.''

''Ohun ti wọn laṣẹ lati kọkọ ṣe ni lati gba aṣẹ ileẹjọ lati fi panpẹ ọba mu ẹnikẹni. Ti ẹni naa ba wa sa mọ wọn lọwọ nigba ti wọn ba n wa lati fi panpẹ ọba mu, ni wọn yoo gba ileẹjọ lọ lati gba aṣẹ ''Mo n wa ọ''.''

''Lai si aṣẹ ileẹjọ, irọ patapata ati iwa ọdaran ti awọn ọtẹlẹmuyẹ ni Naijiria n hu si awọn araalu.''

Pelumi Olajengbesi wa kesi awọn ajọ eto alaabọ ati ọtẹlẹmuyẹ lati tun ile wọn to, ki wọn ye e doju ofin orilẹede Naijiria bọlẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: