Oyo PDP Crisis: Abass Oloko ní igun tó ń fapá jánú kò le dá borí ìbò tẹ́lẹ̀ kí Seyi Makinde tó dé

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde Facebook

Igbakeji alaga fun ajo to n risi eto igbafẹ ni ipinlẹ Oyo, Abass Oloko ti ni awọn igun ẹgbẹ oṣelu to n fi apa janu ni ipinlẹ Oyo lo jẹ alaimoore.

Oloko sọrọ yii lẹyin ti awọn igun kan dibo a nigbẹkẹle ninu rẹ mọ fun gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, ti wọn si ni ko kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.

Oloko ni ọla Makinde ni wọn n jẹ nitori oun lo gba wọn ninu ẹsin ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, nitori ẹgbẹ naa ko bori ninu idibo kankan, ki Seyi Makinde to de si PDP.

Bẹẹ ba gbagbe, iroyin kan lo ni Mulikat Adeola Akande, Nureni Akanbi, Gbolarumi Hazeem, AbdulRasheed Olopoeyan, Femi Babalola pẹlu awọn eekan ẹgbẹ PDP mii lo n fapa janu.

Awọn eeyan yii si lo sepade ni ilu Ibadan, ti wọn si ni awọn yoo ri daju pe Makinde ko gbe asia ẹgbẹ oṣelu PDP lati dije fun saa keji ninu ẹgbẹ oselu naa.

Àkọlé fídíò,

Hijab Female Footballer: Zulfah ní àlá òun ní láti jẹ́ agbábọ́ọ̀lù obìnrin tó dáńtọ́

Amọ, Oloko ni ko si ẹnikan ninu awọn eekan ti wọn tako Makinde naa ti wọn gberi ninu idibo to ti waye ko to di ọdun 2019.

''Ohun ti o dara fun wọn ni lati gba awọn to n ṣiṣẹ, lati tu wọn ninu, ki wọn ma ba pofo''

''Ibanujẹ ọkan lo jẹ fun mi lati ri awọn eekan ati agbaagba to n tako Seyi Makinde.''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

''Wọn ti gbagbe pe ọba ni gomina Seyi Makinde, ko si si ibi to de, ti ko ni gba ade nibẹ.

''Nigba to darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP, moriya lo jẹ fun wọn, to si fi owo ara rẹ ṣeto idibo to gbe e wọle.''

Abass fikun pe, ti akoko ba to, aala yoo fi oko ọlẹ han boya awọn araalu ti Seyi Makinde n gbọ tiwọn ni wọn yoo dibo fun ni, tabi awọn alatako.

Àkọlé fídíò,

Seyi Makinde: Ẹ̀yin tẹ́ fẹ́ fi ọ̀rọ̀ ẹ̀sin ba Oyo jẹ́, ẹ ṣọ́ra ṣe

Amọ o parọwa si awọn to n fi apa janu naa, lati tun ero wọn pa nitori ọpọlọpọ ipo lo ṣi wa ni ipinlẹ naa ti wọn ko tii fi ẹnikẹni sibẹ.

Abass ni o da oun loju pe Gomina Seyi Makinde kii se alaimore ẹda, nitori naa ko le e gbagbe ẹnikẹni, awọn ni ki wọn lọ ṣe suuru.