Ikoyi Collapse Building: Ọ̀rẹ̀ Pásítọ̀ ní oúnjẹ́ ló ń jẹ lọ́wọ́, tí wọn fi pè é kó wá sábẹ́ ilé, kò tó ìṣẹ́jú mẹ́wàá tí ilé fi wó

Oku ẹnikan labẹ ile to wo

Pásítọ̀ ìjọ kan ni ijọ Redeem Omotosho Emmanuel náà sọ pé, akẹgbẹ́ òun kan, Ola Ogunfunwa àti àwọn ènìyàn méjìlélógún tó kó wá láti Ibafo nípìnlẹ̀ Ogun náà wà lábẹ́ ilé náà.

Ogunfuwa tó jẹ́ pásítò ìjọ RCCG Living Water Parish, Ibafo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn onímọ̀-ẹ̀rọ níbí ilé tó ń kọ ilé náà.

Emmanuel sọ pé Ogunfuwa wá pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ méjìlélógún ti wọ́n tún nílò níbi iṣẹ́ náà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Ó pẹ́ tí mò ti wà níbí nítori ọrẹ mi pásítọ̀ tó n ṣiṣẹ́ níbí, onímọ̀ ẹ̀rọ ni. Ó kó àwọn òṣìṣẹ́ bírísopè méjìlélógún wá láti Ibafo láti ṣiṣẹ́ níbi, Birikila, jórinjórín àtàwọn bi ọmọkùnrin méjìlélógún.

Wọ́n tẹ̀lẹ́ wá láti ṣiṣẹ́ kí wọ́n le parí iṣẹ́ náà, wọ́n ba sọ̀rọ̀ pé àwọn nílò iṣẹ́, ó si kó wọ́n wá.

"Títí di àsìkò yìí, láàrín gbogbo àwọn tí wọ́n ti yọ jáde lábẹ́ ilé yìí, kò sí ẹ̀yọ kan lára àwọn ọmọkùnrin náà tó ti jáde yálà, òkú tàbí ààyè"

"Lásìkò ìsìnmi ránpẹ́, ó jáde wá láti jẹ́un, ọ̀gá rẹ kan wá ránṣẹ́ pé, ló fi padà sínu ilé, ko tó iṣẹ́jú mẹ́wàá tó wọlé ni ilé náà wó lulẹ̀.

" Ó si wà níbẹ̀ títí di àsìkò yìí, a sí n gbàdúrà sí Ọlọ́rún kí ó jáde láàyè, a nígbàgbọ́ pé kò sí nǹkan ti Ọlọ́run ko le ṣe.

Ilé alájà mẹ́ẹ̀dógún ni ìjọba Eko búwọ́lù, kìí ṣe alájà mọ́kànlélógún

Ọ̀gá àgbà fajọ to n se ipeniye ile kikọ LABSCA, Gbolahan Oki, tí ijọba ni ko lọ rọkun lẹnu isẹ nitori isẹlẹ naa, lọ́jọ́ ajé ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ilé alájà mẹ́ẹ̀dógún ni ilé iṣẹ́ òun bùwọ́lù kìí ṣe ilé alájà mọ́kànlélógún.

Sùgbọ́n, ìgbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Eko,Ọmọwe Obafemi Hamzat lásíkò tó n sọ̀rọ̀ ló ni ilé alájà mọ̀kànlélógún ni wọ́n búwọ́lù.

Ẹ̀wẹ̀, àwọn òṣìṣẹ̀ pàjáwìrì to n sisẹ idoola ẹmi nibi isẹl naa tí sisẹ wọ ọjọ́ kẹ́ta, ti àwọn iwé tuntun mííràn tún jẹyọ tí ó fi hàn pé, ìjọba ìpínlẹ̀ Eko búwọ́lu ilé alájà mẹ́ẹ̀dógún fún ilé iṣẹ́ náà.

Ìwé náà jẹ́ tí ajọ tó n mójútó ààtòlú àti ilé kíkọ nipínlẹ̀ Eko (Physical Planning Permit Authority).

Iwé ọ̀hún fi hàn pé, àjà mẹ́ẹ̀dógún ló yẹ kí ilé náà dé, ọ̀nà mẹ́tà irú rẹ̀ sí ni ó yẹ kí wọn kọ́ pẹ̀lú.

Ọjọ́ kẹsan oṣù kẹrin ọdún 2019 ni ilé iṣẹ́ náà búwọ́lu iwé ọ̀hún

Kọ́mísọ́nà fétò iròyìn àti ọ̀rọ̀ tó nlọ nipinlẹ Eko, Gbenga Omotosho, sọ pé ìgbìmọ̀ tí ìpínlẹ̀ Eko gbé kalẹ̀ yóò mójútó gbogbo kùdiẹ̀kudiẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ ọhun.

Àkọlé fídíò,

Ikoyi Collapsed Building: Bí ilé alájà mọ̀kànlélógún ṣe dà wó lulẹ̀ ní Ikoyi, l‘Eko rèé

Kò sí ẹni tó mọ ibí ti Femi Osibona wà:

Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tí ìṣẹ̀lẹ̀ aburu yìí ti ṣẹ̀, kò sí ẹni tó lé sọ pé ibi báyìí ni ẹni to ni ilé náà, ìyẹn Femi Osibona wa, bi o tilẹ jẹ pe wọn ló wà ní àjà kéjìdílógún lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ẹ̀wẹ̀, agbẹ̀nusọ àjọ NEMA, Ibrahim Farinloye lọ́ja Isegun sọ pé wọ́n ti ri òkú amúgbálẹ́gbẹ̀ rẹ̀.

Kọmisọna ọlọ́pàá ni ìpínlẹ̀ Eko náà Hakeem Odumosu ni kò sí ẹni tó le sọ pé, ibi kan pàtó ni Femi Osibona wà, bákan náà ni kò si ẹni ri òkú rẹ̀.

Gómìnà ìpińlẹ̀ Eko Babajide Sanwoolu lásìkò tí ó ṣàbẹ̀wò síbi iṣẹ̀lẹ̀ náà lọ́jọ́ru sọ pé àwọn mẹ́sàn mii ni wọ́n ti ri dóòla ni aayè, àti pé, mẹ́tà nínú wọ́n ti kúrò nílé ìwòsàn.

Ó dárúkọ wọn pé Odutan Timileyin, 26; Ahmed Kinleku, 19, (Cotonou, Benin Republic); Sunday Monday, 21; Adeniran Mayowa, 37; Solagbade Nurudeen, 33; àti Waliu Lateef, 32.

Àkọlé fídíò,

Sunday Igboho Herbalist: Agbófinró mẹ́fà ló wọ́lé wá gbé ọmọ mi láì mọ́ ibi tó wà

Ẹ ba wa gbe oku ẹni wa to ku nibi ile to da wo - Awọn mọlẹbi yari

Ó ti di ènìyàn mọ́kànlélógún tó ti dágbéré fáyé níbí ilé alájà mọ́kànlélógún to wó ni ilú Ikoyi nipinlẹ Eko lọ́jọ́ kini oṣù kọkànlá, ọdún 2021.

Ní nǹkan bi aago méjì ọ̀sán ni ilé náà dàwó.

Ìròyìn sọ pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló há sí abẹ́ ilé náà, tó fi mọ́ adarí Fourscore Height Limited, Ọ̀gbẹ́ni Femi osibona tí wan ni òun ló ni ilé náà.

Gómínà ìpińlẹ̀ Eko, Babajude Sanwo-Olu ni iṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ èyí tó kan gbogbo Nàìjíríà nígbà tó fí ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ènìyànmejidinlogoji ni wọ́n ti gbé jáde lókùú nínú ilé náà.

Ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀bí àtí olólùfẹ́ tí wọ́n n wá ẹbí wọn ló n fẹ̀dùn ọ̀kàn wọ́n pé, àwọn ko ni ànfàní láti wọ mọ́súárì Mainland Hospital ni Yaba, láti gba òkú tí wọ́n kó lọ síbẹ̀.

Ọkùnrin kan Jude Ogochukwu tó ń fẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn pé wọ́n kò fún òun ni ààyè láti rí àwọn okú tó wà nibẹ̀ bóyá ẹbi rẹ̀ wà níbẹ̀.

Ó ní òun lọ síbẹ̀ lẹ́yìn ti ìgbákejì Gómínà ìpìnlẹ̀ Eko sọ pé kí àwọn lọ síbẹ̀.

Àkọlé fídíò,

Olugbon Twins: Ọba Alao àti Olorì rẹ̀ bí ìbejì lẹ́yìn tí nǹkan oṣù ti dúró lẹ́ni ọdún 53