Teslim Thunder Balogun: Àwọn oní-Tomato, aláta, oníṣu á máa kó ọjà wọn lọ́fẹ̀ẹ́ sínú ọkọ̀ bàbá mi- Hakeem Teslim-Balogun

Teslim Thunder Balogun: Àwọn oní-Tomato, aláta, oníṣu á máa kó ọjà wọn lọ́fẹ̀ẹ́ sínú ọkọ̀ bàbá mi- Hakeem Teslim-Balogun

"Ó wù ẹ̀, kò wù ẹ́, tí wọ́n bá ti gbọ́ pé ọmọ bíbí Thunder Balogun ni ẹ́, dandan ni wàá gbá bọ́ọ̀lù fún School ẹ".

Ajibola Hakeem Balogun ọmọ gbajugbaja ati ilumọọka agbabọọlu fun orilẹede Naijiria ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin nigba ti aye ṣi wa lorokun, Teslim Balogun gba BBC Yoruba lalejo.

Teslim Balogun ti ọpọlọpọ mọ kaakiri agbaye si Thunder Balogun kẹnu bọ ọrọ lori iyatọ to wa laarin igbe aye baba rẹ gẹgẹ bi irawọ agbabọọlu aye atijọ ati bi awọn ti aye ode oni ṣe n ṣe.

O ni lati kekere ni awọn ọmọ Thunder Balogun ti n gbadun iyi to wa ninu orukọ ati iṣẹ ti baba awọn nṣe.

Bi ileewe kan ba ti fẹ gba wọn fun ẹkọ lati kekere gẹgẹ bo ṣe sọ, “bi wọn ba ti rii pe ọmọ Thunder Balogun ni ẹ, yala o wu ẹ tabi ko wu ẹ o, oo niṣẹ meji, wọn a ni koo niṣo lori ọdan na, afi dandan koo gba bọọlu fun ileewe yẹn”.

“Orúkọ bàbá mi Thunder Balogun máa ń dẹ́rù ba àwọn ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù tí àwa ọmọ rẹ̀ bá kojú”.

O ni awọn imọran ti Baba oun Teslim Balogun maa n fun awọn tayọ gbigbe orukọ rẹ ti gbogbo agbaye n wari fun lọ.

"Taa ba ni ka lọ si ọja lọ ra nkan lasiko ti iya mi ba loyun ti emi ati baba mi lọ, àwọn oní-Tomato, aláta, oníṣu á máa kó ọjà wọn lọ́fẹ̀ẹ́ sínú ọkọ̀ bàbá mi".

O ni iyi ti baba oun ati awọn tawọn jẹ ọmọ maa n ri kii ṣe kekere.

Agbaọjẹ akọroyin aye atijọ kan, Segun Adenuga ti BBC Yoruba bá sọ̀rọ̀, ṣalaye iru agbabọọlu ti Thunder jẹ lori ọdan.

O ni ko si ootọ kankan to jọ pe Thunder Balogun fi ṣọ́ọ̀tì pa aṣọ ojule kankan. Ege lo maa n ge ju koda o fẹẹ le bi aṣọle pe ibo lo fẹ ki oun gba bọọlu wọle si lawọn rẹ sibẹ yoo ṣi tayọ”.

“Laye atijọ, tọkan tara ni wọn fi n gba bọọlu, pe wọn mu wọn lasan pe ki wọn wa gba bọọlu fun orilẹede wọn, iyi nla ni, ko si si ẹni to maa n beere owo, tọrọ kọbọ ni wọn maa n fun wọn”.

Ọmọ Thunder Balogun ṣe afiwe bi awọn gbajumọ irawọ aye ode oni ṣe maa n takete si awọn ololufẹ wọn tabi le wọn danu ti wọn ba ri wọn lawujọ.

“Baba mi maa n sọ nigba taa wa ni kekere pe bọọlu tawọn n gba yii ati bawọn eeyan ṣe fẹran awọn si, kii ṣe bọọlu ori papa nikan o tori gbogbo awọn taa ba fẹ lọ ra nkan lọja lo ma maa pariwo Thunder Thunder ti wọn a maa yọ mọ mi”.

Bakan naa ni ọmọ eekan agbabọọlu gba awọn ọdọ asiko yii to yan bọọlu gbigba gẹgẹ bi iṣẹ layo nimọran.

Akoroyin BBC to ṣe ifọrọwanilẹnuwo yi, Adedayo Ehinmitan lo ya aworan naa pẹlu ọpọlọ