Ugandan soldiers jailed for killing protesters: Ọmọ ogun méjì rí ẹ̀wọ̀n gbére àti ọdún 35 he lẹ́yìn tí wọ́n yìnbọn pa olùfẹ̀hónúhàn mẹ́ta

Ugandan soldiers jailed for killing protesters

Oríṣun àwòrán, Succo/Pixabay

Ile ẹjọ ologun kan ni Uganda ti sọ awọn ọmọ ogun meji si ẹwọn lẹyin ti wọn jẹbi pipa awọn olufẹhonuhan mẹta lọdun 2020.

Ifẹhonuhan naa bẹ silẹ lẹyin ti awọn agbofinro fi ṣikun ofin mu ọkan lara awọn oludije sipo Aarẹ orilẹ-ede naa, Robert Kyagulanyi, ti ọpọ mọ si Bobi Wine, nibi ipolongo ibo kan.

Wọn sọ ọmọ ogun kinni si ẹwọn gbere fun pipa Grace Walungama lẹba ṣọọbu mẹkaliiki kan nitori ọmọ ogun naa ro pe olufẹhonuhan ni.

Ọmọ ogun yii kan naa lo yinbọ tun pa ẹnikeji, Hussein Ssenoga, eyii to jẹ akẹgbẹ rẹ nileeṣẹ ọmọ ogun nitori o kọ lati fi ṣikun ofin mu olufẹhonuhan.

Ni ti ọmọ ogun keji, o wa lara awọn ẹsọ alaabo abẹlẹ, o si gbajumọ lati maa tete yinbọn.

Àkọlé fídíò,

Ṣé lọ́òtọ́ ọkọ àti ìyàwọ́ ní Mr & Mrs Kogberegbe? Àṣírí bí a ṣe ń ṣe ètò yìí rèé...

Ile ẹjọ naa ṣe idajọ ọdun marundinlogoji fun ọmọ ogun ọhun lẹyin to jẹbi pipa Ibrahim Kirevu, eyii to yẹ ko mu lọ si ahamọ ọlọpaa pẹlu irọwọrọsẹ.

Idajọ yii ni akọkọ iru rẹ ti yoo waye lẹyin ti awọn ọmọ ogun ṣina ibọn bilẹ fun awọn olufẹhonuhan ṣaaju idibo Aarẹ naa lọdun 2020.

Àkọlé fídíò,

KieKie

O kere tan, aadọta eeyan lo ba iṣẹlẹ naa lọ.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa sọ lasiko naa pe awọn fi ṣikun ofin mu Bobi Wine lati dena ikojọpọ ọpọ ero nitori arun Coronavirus to n mi gbogbo agbaye titi lasiko naa.

Àkọlé fídíò,

Ìdí tí Tòmátò ẹ̀sà kò ṣe dára fún ìlera yín; wo àwọn kókó márùn-ún yìí

Bobi Wine koju Aarẹ Yoweri Museveni ninu idibo ọhun lẹyin to ti n tukọ orilẹ-ede naa bọ lati ọdun 1986.

Lẹyinorẹyin, Museveni lo jawe olubori ninu eto idibo naa ti wọn si bura wọle fun, iyẹn fun saa kẹfa lori alefa.

Àkọlé fídíò,

FUTA First Class Twins