Ǹkan melòó ní o rántí ní ọdún 2018

Ṣe àwọn ìdánwò wa yìí láti mọ̀

Àwọn ìdáhùn wà ní ìsàlẹ̀

Ìbéèrè 1/12

Kíní orúkọ abẹnugàn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin tó pàsẹ pé ki PSP maa kolẹ̀-kódòtí padà ní ìpínlẹ̀ Eko

1. Mudashiru Obasa
2. Femi Gbajabiamila
3. Desmond Elliot
4. Temidayo OlofinsawoÌbéèrè 2/12

Ìpínlẹ̀ wo ni ilé Adẹ́tẹ̀ tí Tunji Oluwatimileyin tó jẹ́ kọngila tẹ́lẹ̀ rí wà

1. Kwara
2. Ondo
3. Lagos
4. IbadanÌbéèrè 3/12

Tani gbájúgbajà sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó bu ẹnú àtẹ́ lú ọ̀rọ̀ ìdámẹ́wàá

1. Toke Makinwa
2. Morayo Brown
3. Daddy Freeze
4. Maope OgunÌbéèrè 4/12

Adẹ́rìn pòsónú wo ní ó sọ pé ọwọ́ bàbá òun ní òun ti kọ́ iṣẹ́ àwàdà síṣe, ó ti di ìlúmọ̀ká lórí instagram

1. Broda Shaggi
2. Folarin Falana (Falz)
3. Kenny Blac
4. Seyi LawÌbéèrè 5/12

Lola Alao sàlàyé ìkú tó pa gbájúgbajà òṣèrè Aisha Abimbọla ọmọge Campus), irú ikú wo gan ló paa

1. Jẹjẹrẹ ọyàn
2. Àisan Ibà
3. Ẹjẹ̀ ríru
4. Àisan ọkànÌbéèrè 6/12

Kíni orúkọ ààfáà tó dólàà àwọn kìrìsìtẹ̀ní láti kó wọn pamọ síní mọsálásí ní ìpínlẹ̀ Plateau lásìkò rògbòdìyàn

1. Shekau Abubakar
2. Shuaib Bello
3. Muktar Ali
4. Muhammed AliÌbéèrè 7/12

Adúgbò wo ní ibùdó ìwé títẹ̀ àkọ́kọ́ ní ìwọ̀orùn ilẹ̀ Afíríkà

1. Shomolu ní ìpínlẹ̀ Eko
2. Yaba
3. Ikoyi
4. ObalendeÌbéèrè 8/12

Alága ẹgbẹ́ wo ní Fele tó kú ni ìlú Ibadan lójọ́ si

1. Alága ẹgbẹ́ ọlọ́kada
2. Alága ẹgbẹ́ NURTW
3. Alága ẹgbẹ́ RTAN
4. Alága ẹgbẹ́ MaruwaÌbéèrè 9/12

Kíní àkọlé eré tí gbájúgbajà òṣèré tíátà Femi Aebayo fi gba àmi ẹyẹ AMVCA ọdún 2018.

1. Bata wahala
2. Okola onituwo
3. Etiko onigedu
4. KoredeÌbéèrè 10/12

Ìlú àti ìpínlẹ̀ wó ní ibéji tí pọ̀jù lọ ní orilẹ̀-èdè Nàìjíríà

1. Igboho ní ìpínlẹ̀ Oyo
2. Iṣẹyin ní ìpínlẹ̀ Oyo
3. Ibadan ni ìpínlẹ̀ Oyo
4. Igbo ọrà ní ìpínlẹ̀ OyoÌbéèrè 11/12

Èló ní ìjọba apapọ̀ pinu láti fi ràn àwọn àgbẹ̀ onírẹsì lọ́wọ́ láti fi kún iṣẹ́ ọ̀gbìn wọn

1. Ọgọ́ta Bílíọ̀nù Náírà
2. Ẹgbẹ̀rún Bílíọ̀nù Náírà
3. Igba Mílíọ̀nù Náírà
4. Àádọ́ta Bílíọ̀nù NáíràÌbéèrè 12/12

Orílẹ̀-èdè wo ní ọmọ ọdún méje tí gbé bàbá rẹ̀ lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá nitorí ọ̀rọ̀ ilé ìgbọ̀nsẹ̀

1. Germany
2. India
3. Nigeria
4. FranceÀwọn ìdáhùn

1. Kíní orúkọ abẹnugàn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin tó pàsẹ pé ki PSP maa kolẹ̀-kódòtí padà ní ìpínlẹ̀ Eko

ìdáhùn: Mudashiru Obasa

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Eko ti paṣẹ̀ pé kí ile iṣẹ́ aládani Private Sector Patnership (PSP) bẹ̀rẹ̀ kíkó ìdọ̀tí padà ní ìpínlẹ̀ Eko.


2. Ìpínlẹ̀ wo ni ilé Adẹ́tẹ̀ tí Tunji Oluwatimileyin tó jẹ́ kọngila tẹ́lẹ̀ rí wà

ìdáhùn: Ondo

Adetunji Oluwatimilẹyin jẹ́ kọgila tẹ́lẹ̀rí kí ó to ṣe àkíyèsí pé òun ní ààrùn ẹ̀tẹ̀ tó fí di ẹni tó ń gbé Leper's colony ní ìpínlẹ̀ Ondo.


3. Tani gbájúgbajà sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó bu ẹnú àtẹ́ lú ọ̀rọ̀ ìdámẹ́wàá

ìdáhùn: Daddy Freeze

Daddy freeze jé gbájúgbajà sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó máá ń bu ẹnú àtẹ́ lu ìdámẹ́wáà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà


4. Adẹ́rìn pòsónú wo ní ó sọ pé ọwọ́ bàbá òun ní òun ti kọ́ iṣẹ́ àwàdà síṣe, ó ti di ìlúmọ̀ká lórí instagram

ìdáhùn: Broda Shaggi

Gbajugbaja apanilẹrin loju opo ikansiraẹni Instagram, to tun jẹ osere tiata, Samuel Animasahun Perry salaye pe, ẹnu awọn agbero ni gareji ọkọ ero ni ero lilo inagijẹ ninu ere ti kọkọ gba ọkan oun.


5. Lola Alao sàlàyé ìkú tó pa gbájúgbajà òṣèrè Aisha Abimbọla ọmọge Campus), irú ikú wo gan ló paa

ìdáhùn: Jẹjẹrẹ ọyàn

Gbajúgbajà òṣèré tíátà Yoruba obìnrín nì, Lola Alao, tó tún jẹ́ ọ̀rẹ́ timọ-timọ pẹlu olóògbé Aishat Abimbola tó jáde láyé, lẹ́yin tí ó ní ààrùn jẹjẹrẹ ọyàn, ti sọ̀rọ̀ lórí ikú ọrẹ́ rẹ̀.


6. Kíni orúkọ ààfáà tó dólàà àwọn kìrìsìtẹ̀ní láti kó wọn pamọ síní mọsálásí ní ìpínlẹ̀ Plateau lásìkò rògbòdìyàn

ìdáhùn: Muhammed Ali

Nígba tí aafa alaanu yii rii tí ogunlọ́gọ̀ àwọn ènìyàn ń sá wọ abúle rẹ̀ ní Nghar Yelwa ní Ìpínlẹ̀ Plateau l'ọjọ́ Aikú, kò ròó lẹ́ẹ̀méjì to fi ṣílẹ̀kùn láti gbà wọ́n wọlé.


7. Adúgbò wo ní ibùdó ìwé títẹ̀ àkọ́kọ́ ní ìwọ̀orùn ilẹ̀ Afíríkà

ìdáhùn: Shomolu ní ìpínlẹ̀ Eko

BBC Yorùbá dé àdúgbò Sómólú ní ìlú Èkó, níbi tí ọ̀pọ̀ ilé ìtẹ̀wé pọ̀ sí jùlọ ní ẹkùn ìwọ̀ òòrùn Afrika. A gbọ́ pé ìwé títẹ̀ ní Sómólú dára ju èyí tí wọn tẹ̀ ní ilẹ̀ òkèèrè bíi orílẹ̀-èdè China lọ.


8. Alága ẹgbẹ́ wo ní Fele tó kú ni ìlú Ibadan lójọ́ si

ìdáhùn: Alága ẹgbẹ́ NURTW

Ọpọ awọn eekan ẹgbẹ awakọ ero lorilẹede Naijiria ni wọn peju sibi isinku oloogbe Taofeek Oyerinde ti pupọ eeyan mọ si Fẹlẹ.


9. Kíní àkọlé eré tí gbájúgbajà òṣèré tíátà Femi Aebayo fi gba àmi ẹyẹ AMVCA ọdún 2018.

ìdáhùn: Etiko onigedu

Wọ́n yan òṣèré Femi Adebayo pẹ̀lú bàbá rẹ̀, Adebayo Salami fún àmì ẹ̀yẹ yìí sùgbọ́n bàbá ti sọ fún ọmọ rẹ̀ nílé pé kó lọ mú òun orí òun wú, Femi náà sì ló pegedé


10. Ìlú àti ìpínlẹ̀ wó ní ibéji tí pọ̀jù lọ ní orilẹ̀-èdè Nàìjíríà

ìdáhùn: Igbo ọrà ní ìpínlẹ̀ Oyo

Awọn ibeji to ba BBC Yoruba sọrọ ni ilu Igbo Ọra, lasiko ọdun ibeji to waye nibẹ ni, orisa ni ibeji, obi ti ko ba si gbe awọn jo kiri laye atijọ yoo se aisan.


11. Èló ní ìjọba apapọ̀ pinu láti fi ràn àwọn àgbẹ̀ onírẹsì lọ́wọ́ láti fi kún iṣẹ́ ọ̀gbìn wọn

ìdáhùn: Ọgọ́ta Bílíọ̀nù Náírà

Mínísítà feto ọ̀gbìn, Audu Ogbeh ní ìjọba àpapọ̀ tí buwọ́lu ọgọ́ta bílíọ̀nù náírà gẹ́gẹ́ bíi owó iranwọ fún ìpèsè ìrẹsì ní orílẹ́-èdè Nàìjíríà.


12. Orílẹ̀-èdè wo ní ọmọ ọdún méje tí gbé bàbá rẹ̀ lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá nitorí ọ̀rọ̀ ilé ìgbọ̀nsẹ̀

ìdáhùn: India

Hanifa Zaara ní bàbá òun parọ́ pé yóò kọ́ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tí òun bá se dáradára ní ilé ìwé, àmọ́ bàbá rẹ̀ kọ̀.


 • JAN
 • FEB
 • MAR
 • APR
 • MAY
 • JUN
 • JUL
 • AUG
 • SEP
 • OCT
 • NOV
 • DEC

Ǹkan melòó ní o rántí ní ọdún 2018

Ṣe àwọn ìdánwò wa yìí láti mọ̀

Iye ti ó gbà:
O gba