Coronavirus

 1. Coronavirus: Òṣìṣeẹ́ ọgbà ẹranko kó àrùn Coronavirus ran ẹkùn nílùú New York

  Ẹkun kan ni ọgba ̣eranko to wa ni Bronx, ni ilu New York ti fara kaasa arun Coronavirus.

  Ẹkun ọhun ti orukọ rẹ n jẹ Nadia, ni awọn onimọ gbagbọ pe o jẹ ẹranko akọkọ ti yoo kọ lugbadi arun naa nilẹ Amẹrika.

  Awọn alaṣẹ ọgba ̣eranko naa ni ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ awọn ẹranko to wan i ipinlẹ Iowa lo fidi esi ayẹwo ti wọn ṣe fun ẹkun ọhun mulẹ.

  Amọtẹkun

  Wọn sọ pe oṣiṣẹ ọgba ẹranko naa kan lo ko arun ọhun ran ẹkun naa ati awọn ẹranko mẹfa miran.

  Wọn ṣalaye pe Nadia bẹrẹ si n ṣafihan apẹrẹ arun Coronavirus bi ikọ efe, ni ipari oṣu to kọja lẹyin ti oṣiṣẹ naa ti wọn ko tii mọ fọwọ kan an.

  Olori awọn oṣiṣẹ ọgba ẹranko naa, Paul Calle sọ fun awọn oniroyin pe “Eyi ni igba akọkọ ti a ma gbọ ni gbogbo agbye pe eeyan ko aisan ran eranko.”

  Bo tilẹ jẹ pe awọn onimọ sọ pe ko ti si ẹri pe awọn ẹranko lee ni arun Coronavirus tabi ko ran eeyan, ṣugbọn iroyi fi idi rẹ mulẹ pe awọn ẹrank kan ti ni arun naa lawọn ibi kan lagbaye.

 2. Ojúlalákàn fi ń ṣọ́rí, Coronavirus kò mojú ẹnikẹ́ni-Gómìnà Dàpọ̀ Abíọ́dún

  Ojúlalákàn fi ń ṣọ́rí, Coronavirus kò mojú ẹnikẹ́ni; Gómìnà, Dàpọ̀ Abíọ́dún ṣèkìlọ̀ fáwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ògùn.

  Ẹ wòó nínú fídíò ìsàlẹ̀ yìí👇👇👇

  Video content

  Video caption: Ojúlalákàn fi ń ṣọ́rí, Coronavirus kò mojú ẹnikẹ́ni; Gómìnà, Dàpọ̀ Abíọ́dún ṣèkìlọ̀
 3. Ìpínlẹ̀ Eko pèsè ètò ìlera ọ̀fẹ́ fún àwọn aláboyún

  Gomina ipinle Eko. Babajide Sanwo-Olu ti pase eto iwosan ofe fun awon alaisan ati awọn alaboyun to ba ti lo si ile iwosan ijoba ni ipinle naa.

  Gomina Babajide Sanwo-olu fi lede bẹẹ loju ẹrọ ikansiraẹni Twitter wọn.

  Gomina Sanwo Olu ni awọ̀n yoo san owo iwosan awọn ti wọ̀n ba ṣiṣẹ abẹ fun ati awọn ti wọn ba n gba itọju pajawiri lọwọ.

  gomina babajide sanwoolu

  Bakan naa ni gomina naa ni awon alaboyun to ba fe bimo, yala iṣẹ abẹ ko gbẹyin ninu eto yii.

  Gomina naa ni eyi yio tun mu irorun ba awon eniyan lasiko igbele lati kapa itankalẹ arun Coronavirus.

  View more on twitter