Ipinlẹ Abia

 1. KókóIlé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà wọ́gilé ẹ̀wọ̀n Orji Uzor Kalu, pàṣẹ ìgbẹ́jọ́ tuntun

  Uzor Kalu atawọn ẹṣọ agbofinro

  Ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria ti wọgile idajọ ẹwọn ọdun mejila ati gbigbẹsẹle dukia ti ile ẹjọ gbe le gomina ipinlẹ Abia tẹlẹ Orji Uzor Kalu.

  Gbogbo adajọ mejeeje to joko lori igbẹjọ naa ni wọn fohun ṣọkan pe ile ẹjs giga apapọ ilu Eko to gbe idajọ kalẹ pe Kalu, ileeṣẹ rẹ Slok Nigeria Limited ati oludari eto iṣuna tẹlẹ nipinlẹ Abia, Jones Udeogu jẹbi ẹsun kiko ipinlẹ Abia owo to le ni biliọnu meje naira jẹ.

  Uzor Kalu

  Ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria woye pe Onidajọ Mohammed Liman to dajọ naa kii ṣe adajọ mọ nigba to gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ naa.

  O ni niwọn igba to jẹ pe wọn ti gbe Onidajọ Liman ga lọ si ile ẹjọ kotẹmilọrun ṣaaju igba naa, ko lẹtọ mọ lati pada lọ gbọ ẹjọ naa tabi gbe idajọ kalẹ lori rẹ. Ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria woye pe aṣẹ ti aarẹ ile ẹjọ kotẹmilọrun fun un pe ko lọ gbs ẹjọ naa labẹ ofin iṣedajọ lorilẹede Naijiria ko ba ofin mu.

  Ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria wa wọgile idajọ naa pẹlu aṣẹ pe ki wọn lọ tun ẹjọ naa gbọ lati ibẹrẹ

 2. Ibrahim Umar

  Umar ni oun wa nile iwosan fun ọpọ oṣu nibi ti oun ti gba itọju, ṣugbọn awọn dokita sọ fun oun pe ọta naa wa lori iṣan ọrun oun.

  Kà Síwájú Síi
  next