Iranlọwọ latilẹ Okeere

 1. Bí àwọn ènìyàn ṣe ń fún moọ́ ara wọn níbùgbé àwọn ogúnléndé le à fa ìtànkáleẹ̀ Coronavirus -UN

  Awọn ero ni ibudo ogunlende kan lapa oke ọya NAijiria.

  Ẹka Ajọ Isọkan agbaye to n risi etọ ọmọniyan lagbaye, OCHA ti ṣe ikilọ lori bi awọn eniyan ṣe funmọ ara wọn ni awọn ile igbele awọn ogunlende lorilẹede Naijiria.

  Ajọ naa ni o le ṣe okunfa itankalẹ ajakalẹ arun Coronavirus ni awọn ile igbele yii.

  Adari ẹka naa ni Naijiria, Edward Kallon, ninu atẹjade to fi lede, kesi awọn ti ọrọ naa kan lati tete wa ọna abayọ si iṣoro ọhun.

  Awọn ero ni ibudo ogunlende kan lapa oke ọya NAijiria.

  Kallon ni ohun ẹru ni yoo jẹ ti ẹnikan ninu awọn eniyan to le ni miliọnu kan ba ni arun Coronavirus ni awọn ibugbe awọn ogunlende to wa ni ipinlẹ Borno, Adamawa ati Yobe.

  O fikun pe awọn obinrin ati ọmọde ti iye ọjọ ori wọn ko i tii ju ọdun marun lọ,ni wọn poju ni ibugbe awọn ogunlende ni ilu Borno.

 2. Àwọ̀n bàbálọ́jà, ìyálọ́jà ló gba kọngílá ayédèrú ìrẹsì tí ìjọba pín l'Ọ́ṣun-Ìjọba

  Adegboyega Oyetola

  Awọn babalọja ati iyalọja ni ojọba ipinlẹ Ọṣun gbe kongila ipese irẹsi ti wọn pin fawọn eeyan ipinlẹ naa eleyii to ti da ọpọlọpọ awuyewuye silẹ bayii ni ipinlẹ naa.

  Agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Ọṣun, ọgbẹni Ismail Omipidan lo sọ eyi di mimọ ninu ifẹrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba.

  Ni ọsẹ to kọja ni ijọba ipinlẹ Ọṣun bẹrẹ pinpin awọn oun amayedẹrun fawọn eeyan ipinlẹ naa lati bomi tu irora igbele ti wọn n la kọja.

  Adegboyega Oyetola

  Amọṣa ariwo ayederu irẹsi lo gbode eleyi ti ijọba ipinlẹ naa ni oun yoo ṣe iwadii ohun to mu ayederu irẹsi wọ awọn irẹsi ti wọn pin fun araalu.

  Agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ naa wa ṣalaye pe ki owo ilu maa baa gbe sita lawọn fi gbe iṣẹ agbaṣe rira awọn irẹsi naa fun awọn ọlọja ni ipinlẹ Ọṣun