Orilẹede Lesotho

 1. "Nigeria vs Lesotho prediction"

  Ìrètí ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lù Super Eagles ni láti parí ifẹsẹwọnsẹ wọ́n fún pégedé Idije Afcon èyí sì ni láti borí Ikọ̀ Crocoldile Lesotho.

  Kà Síwájú Síi
  next
 2. Coronavirus ti kárí Áfíríkà, ó pàpà wọ orílẹ̀èdè Lesotho

  Olootu ijọ orilẹede Lesotho

  Lẹyin o rẹ yin, Orilẹ-ede Lesotho ti ni akọsilẹ aarun coronavirus, eyi to mu ki orilẹ-ede naa di orilẹ-ede ti aarun naa de kẹyin nilẹ Afirika.

  Iyalẹnu lo jẹ tẹlẹ pe ko si aarun coronavirus ni Lesotho, bi-o-ti-lẹ-jẹ pe orilẹ-ede South Africa to yi i ka ti ni akọsilẹ ẹgbẹrun mọkanla ati ọtalelọọdunrun din mẹwa eniyan to ni aarun naa.

  Lara esi ayẹwo ti wọn ṣe fun awọn arinrin-ajo mọkanlelọgọrin to wa lati South Africa ati Saudi Arabia, ni wọn ti ri ẹni naa.

  Ọpọlọpọ ibeere lo ti jade fun lọpọlọpọ ọsẹ pe bawo ni Lesotho ṣe n ṣe e ti aarun yii ko fi wọ ibẹ botilẹjẹ pe awọn eniyan n wọle-jade si South Africa.

  Ọpọ ero pejọpọ ni orilẹede Lesotho

  Ẹgbẹẹgbẹrun awọn ọmọ orilẹ-ede Lesotho si lo n sisẹ ni South Africa.

  Ni ṣe ni Lesotho ti ibode rẹ pa lasiko ti oun ati South Africa bẹrẹ isede ni opin oṣu Kẹta, to si jẹ pe awọn ti isẹ wọn jẹ koṣeemani nikan lo n lọ, to n bọ. L'ọsẹ diẹ sẹyin, Minisita fun eto inawo ni Lesotho, Moeketsi Majoro lasiko ifọrọwanilẹnu kan, bẹ ẹ awọn ọmọ orilẹ-ede naa to fẹ ẹ pada sile lati South Africa pe ki wọn o duro si ọhun nitori ibẹru pe awọn kan lara wọn le ko aarun naa wọle.

  Bakan naa lo sọ pe wiwọle ti aarun naa ti wọle si ẹ bayii yoo tubọ mu ki ẹrù ko wọ eto ilera rẹ ti ko pojuowo l'ọrun.

  Orilẹ-ede Lesotho ko ni eroja lati sayẹwo aarun Covid-19, orilẹ-ede South Africa lo ti maa n lọ ṣe e.

  Minisita naa sọ pe awọn ti fi eroja ti wọn gba lara eniyan mẹtadinlẹgbẹta ranṣẹ fun ayẹwo, marundinlọọdunrun ni ko ni i, esi mọkanlelọọdunrun ko ti i jade.

 3. Victor Osimhen atawọn akẹgbẹ rẹ

  Ẹgbẹ agbabọọlu Lesotho ti wọn n pe ni Crocodiles ta ọmi 1-1 pẹlu Sierra Leone l'Ọjọru ninu ifẹsẹwọnsẹ lati pegede fun idije 2021 AFCON.

  Kà Síwájú Síi
  next